Awuyewuye lórí ìrẹsì tí wọ́n ní ó ń pààyàn láti Seme

Awuyewuye lórí ìrẹsì tí wọ́n ní ó ń pààyàn láti Seme

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìròyìn tó ń milẹ̀ tìtì káàkiri Nàìjíríà lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí ni pé àwọn èèyàn kò gbọdọ̀ jẹ ìrẹsì mọ́.

Ninu iroyin naa ti awọn eeyan n pin kiri loju opo WhatsApp ni a ti gbọ pe ẹnikẹni to ba jẹ irẹsi yoo ku.

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ ṣaaju, ẹnikan ni wọn ji irẹsi rẹ lọ ninu tirela meji to si lọ bẹ ogun lọwẹ pe ki ogun ba oun pa gbogbo awọn to ba ji irẹsi naa ko, to fi mọ ẹnikẹni to ba ra irẹsi ọhun lati jẹ
Eredi ree ti awọn eeyan kan ṣe n fi atẹjiṣẹ ṣọwọ si awọn eeyan wọn pe wọn ko gbọdọ fi ẹnu kan irẹsi lasiko yii ki wọn ma ba ku iku ojiji.

Ninu awọn atẹjiṣẹ naa ti akọroyin gbọ ni ọkunrin kan ti sọ pe ẹni to ba fẹ lọ ra irẹsi ninu ọja ko gbọdọ ra eyii ti wọn ṣẹṣẹ ko wọle, bikoṣe eyii to ti wa lori igba fun ọjọ pipẹ ki irufẹ ẹni bẹẹ ma ba pin ninu iku ojiji ọhun.

Amọ ṣa, ṣee lootọ ni awọn kan ji tirela meji ti irẹsi kun inu rẹ lorilẹ Benin Republic ti ẹni to ni irẹsi naa si lọ bẹ ogun lọwẹ lati maa pa gbogbo awọn to ji irẹsi naa atawọn to ba ra ninu rẹ lati jẹ?

Eyi lo mu ki akọroyin kan si igboro ni Benin Republic lati ba awọn olugbe orilẹede naa sọrọ latari ṣawari ododo.
Awọn olugbe ilẹ naa to sọrọ lati mọ boya lootọ ni awọn eeyan n ku latari pe wọn jẹ irẹsi, wọn ni ko si ohun to jọ bẹẹ.

Ọkan ninu awọn to ba wa sọrọ, Ajia Adue to jẹ oniṣowo irẹsi ni Kotonu sọ pe “Ko si ohun to jọ pe wọn ji irẹsi nibi pe wọn lọ ta a ni Naijiria.

“Lati igba ti wọn ti tilẹkun ibode Naijiria, ọja naa ko da bii ti tẹlẹ, ko si si irẹsi kankan ni cotonou ti a ko lọ si Naijiria.”

Ẹlomiran ti a tun ba sọrọ, Iyaafin Olori Adekemi to n ta ọja ni Seme sọ pe o ṣoro ki odidi tirela irẹsi meji kọja ni Seme ki awọn ẹṣọ aṣọbode ma mu irufẹ tirela bẹẹ lẹyin ti ijọba ti fofin de kiko irẹsi wọle si Naijiria.

Adekemi ni awuyewuye lasan ni ọrọ to n lọ nigboro nipa ọrọ irẹsi ọhun ati pe ṣababi lasan ni iku awọn ti iroyin ni irẹsi lo n pa wọn.

O ni “Koda, emi ṣi jẹ irẹsi lonii, irẹsi ko le wọn ki a ma jẹ irẹsi.

“Awuyewuye lasan ni pe awọn kan ji irẹsi ti ẹnikan si lọ bẹ ogun nitori ọrọ naa, ko si ohun to jọ bẹẹ.”

Abiodun Fareed Ayodele ti ọpọ eeyan mọ si Faredo ni Benin naa sọ si ọrọ ọhun.

O ni lootọ loun naa gbọ iroyin naa amọ oun ko gbagbọ latari bo ṣe ṣoro lati gbe irẹsi wọ Naijiria lati Seme lasiko yii, anbelete odidi tirela meji.

Faredo sọ pe “Irẹsi ti eeyan fi owo ra gan ti eeyan ba fẹ gbe wọle niṣe ni wọn maa mu bi igba ti ẹni naa gbe oogun oloro cocaine, ka to maa sọ odidi tirela meji.

“Nibo lo gba wọle si Naijiria? Ẹni to ni tirela irẹsi meji gan nibo lo gbe si ti wọn ti lọ ji?”

Faredo pari ọrọ rẹ pe ti eeyan ba gbọ iroyin o yẹ ki eeyan maa gbe iroyin wo daadaa ko to mu eyii ti yoo gbagbọ ninu rẹ.
Ninu ọrọ ileeṣẹ aṣọbode ilẹ wa (Nigerian Customs Service), ẹka tipinlẹ Eko ati Ogun, wọn ni irọ pata ni iroyin naa.

Atẹjade ti Alukoro ileeṣẹ aṣọbode, ẹka ti Seme, Isah Sulaiman; fi sita ṣalaye pe iroyin aṣinilọna, ofege ti ko si otitọ kankan nibẹ ni pe irẹsi n pa eeyan.

“Ileeṣẹ aṣọbode ilẹ Naijiria ti gbọ nipa iroyin ofege kan to ni ẹka wa gba irẹsi kan lọwọ ẹni to ni i, a si n pin i ka lai jẹ ki ẹni to ni ọja naa mọ nipa rẹ.

“Iroyin irọ naa tun sọ pe ẹni to ni ọja naa lọ ọ bẹ Ogun lọwẹ si i, awọn eeyan wa n ku, ṣọja kan tun ku ni Badagry.

“Ileeṣẹ aṣọbode n fi gbogbo ẹnu sọ ọ pe irọ gbuu leyi, ẹtan ti ko ni otitọ kan ninu ni pẹlu”

Bakan naa ni ọga gba pata fun olu ileeṣẹ aṣọbode to wa ni Seme; Ben Oramalugo, sọ pe:

“Ko si iṣẹlẹ iru eyi kankan to ṣẹlẹ laaarin wa tabi lọdọ awọn oṣiṣẹ wa.

“O ba ni lọkan jẹ pe awọn kan ti wọn pe ara wọn ni akọroyin n gbe ohun ti ko ri bẹẹ jade.

Wọn si n ko ipaya ba awọn eeyan.”

O rọ araalu lati ma ṣe gba ahesọ gbọ bi iroyin tootọ, ki wọn ma si ba awọn opurọ pin ohun ti ko ṣẹlẹ kiri.

“Iṣẹ wa gẹgẹ bi aṣọbode ni lati da aabo bo ẹnu ibode wa, ki ọja to le fa ijamba ma baa wọle wa. Ohun ti a si duro ṣinsin le lori naa niyẹn.”

Bẹẹ ni ọga aṣọbode ẹka ẹnu ibode Seme naa wi