Àwọn tó pa ọkùnrin tó ni otẹẹli Water ti jẹ́wọ́ bí wọ́n ṣe gbẹ̀mí ẹ̀

Àwọn tó  pa ọkùnrin tó ni otẹẹli Water ti jẹ́wọ́ bí wọ́n ṣe gbẹ̀mí ẹ̀
Fẹ́mi Akínṣọlá
 Àṣé lóòótọ́ ni pé ẹgbẹ̀rún Sàámú kò lè sá mọ́ Ọlọ́run lọ́wọ́, èyí ló se rẹ́gí ìṣẹlẹ̀ bí ọwọ́ ṣe tẹ àwọn ọ̀rẹ́ méjì kan tí wọ́n jingíri nínú ìbálòpọ̀ eléèyàn mẹ́ta tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, tí wọ́n ṣekú pa Adeniyi Ojo, ọkùnrin tó ni òtẹ́ẹ̀lì kan tí wọ́n ń pè ní Water View, tó wà lágbègbè GRA, nílùú Ìlọrin, ní ìpínlẹ̀ Kwara.
Bíi àjẹ́ tó jẹ  èèpo ọ̀bọ̀ làwọn afurasí ọ̀hún,
Joseph Joy Adama, àti Vandora Davies Ọrẹoluwa Favour, ti
ń kà báyìí, lẹ́yìn tọ́wọ́ tẹ̀ wọ́n ní Mowe Ibafo, ní ìpínlẹ̀ Ogun, tí wọ́n sá lọ lẹ́yìn tí wọ́n hùwà burúkú yìí.
Alukoro iléeṣẹ́ ọlọ́pàá àpapọ̀ nílẹ̀ wa, ACP Olumuyiwa Adejọbi, ló ṣàfihàn àwọn ọ̀daràn méjèèjì yìí pẹ̀lú àwọn afurasí mìíràn nílùú Abuja. Ó ní lọ́jọ́ kẹfà, oṣù Kẹwàá, ọdún yìí, lọwọ́ tẹ̀ àwọn afurasí méjèèjì, Adama àti Favour, tí wọ́n jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ilé-ẹ̀kọ́ Gbogbonìse tìpínlẹ̀ Kwara (Kwara State Polytechnic), lórí ọ̀rọ̀ tó ní í ṣe pẹ̀lú ikú Ọ̀gbẹ́ni Adeniyi Ojo, tó ni òtẹ́ẹ̀lì Water View, n’llọrin.
Ó ṣàlàyé pé lẹ́yìn táwọn afurasí yìí ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú olóògbé tán, tí wọ́n bèèrè owó lọ́wọ́ rẹ̀, bọ́yá ìyẹn kò tètè fún wọn, ni wọ́n bá rọ ọ́ lọ́tí yó kí wọ́n lè rí i jà lólè, nìyẹn bá gba ibẹ̀ kú.
Nígbà tí ọ̀kan nínú wọn, Adama, ń bá àwọn oníròyìn ṣọ̀rọ̀, ó ní òun àti Adeniyi ti máa ń bá ara àwọn ní  àṣepọ́ ọjọ́ ti pẹ́, ó ní oníbàárà òun ni, ṣùgbọ́n lọ́jọ́ tí ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú náà wáyé, àwọn lọ sí òtẹ́ẹ̀lì rẹ̀ láti lọ̀ọ́ jà á lólè ni, nígbà tí kò fẹ́ gbà lẹ́rọ̀ làwọn rọ ọ́ lọ́tí yó, táwọn sì jí fóònù àti àwọn ẹrù rẹ̀ mìíràn kó lọ káwọn tóó padà gbọ́ pé  ó ti kú.