Àwọn ọba alayé ilẹ̀ Yorùbá tó lo, ó kéré tán àádọ́ta ọdún lórí ìtẹ́
Fẹ́mi Akínṣọlá
Tó! Tó! Tó! Ká bií ò sí o.Èdùwà nìkan ló lè bi ọba.
Adé orí la fi ń mọ ọba, ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn lá fi ń mọ ìjòyè, àgbà ni tara la fi ń mọ àgbà. Yẹpẹrẹ kí eku aṣín ni àpèrè ọba papàá jùlọ nílẹ̀ yorùbá.
Ní ilẹ̀ Yorùbá, ipò pàtàkì ni àwọn ọba wà nítorí ọba ni olórí ìlú, aláṣẹ, apàṣẹ wà á.
Ọba ní olórí ìlú, ohun tí ọba bá sọ ni abẹ gé nílẹ̀ Yorùbá, tí kò sí ẹni tó lè yipadà tàbí yẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ wò bí ó tilẹ jẹ pé ayípadà tí ń bá àṣà yìí látàrí ìsesí àwọn olóṣèlú onímọtaraẹni nìkan tí wọ́n fẹ dojú àṣà yorúbá bolẹ̀.
Ipò jẹ́ ipò tí kò lọ́jọ́, ẹni tó bá ti jẹ ọba máa ń jẹ ẹ́ di ọjọ́ ogbó títí tí ọlọ́jọ́ máa fi de.
Dídágbà di ọjọ́ ogbó jẹ́ ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń tọrọ lọ́wọ́ Elédùmarè tí èyí kò sì yọ àwọn ọba náà sílẹ̀.
Ọba Stephen Adegoke Egunjobi II – Alafo ti ìlú Afo
Alafo ti ìlú Afo, Ọba Stephen Adegoke Egunjobi Keji ni Ọba ilẹ̀ Yorùbá tó wà láàyè, tó sì ti pẹ́ lórí oyè jùlọ.
Ìwádìí tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Alafo ni Ọba tó wà láàyè tó pẹ̀ lórí oyè jùlọ ní Nàìjíríà báyìí.
Ní ọdún 1958, ṣaájú kí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tó gba òmìnira lọ́dún 1960 ni Ọba Egunjobi jẹ ọba ìlú Afo, ìjọba ìbílẹ̀ Ose ní ìpínlẹ̀ Ondo.
Ọba Egunjobi II ti lo ọdún mẹ́rìndínláàádọ́rin lórí ipò àwọn baba rẹ̀ báyìí.
Oba James Adelusi Aladesuru II – Onigede ti Igede-Ekiti
Ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹfà, ọdún 1959 ni Oba James Adelusi Aladesuru II gorí àpèrè àwọn babańla rẹ̀ gẹ́gẹ́ Onigede ti Igede-Ekiti.
Ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ni Ọba Oba James Adelusi Aladesuru II wà nígbà tó gorí ìtẹ́ ọba.
Níbi ayẹyẹ àádọ́rùn-ún Ọba James Aladesuru II tó wáyé lọ́dún 2023 ni Ọba náà ti sọ pé ẹ̀mí gígùn jẹ́ ohun tó máa ń tọ ìran àwọn nítorí àwọn òbí òun náà gùn púpọ̀.
Gẹ́gẹ́ bí ìtàn ṣe sọ, bàbá Ọba Aladesuru II, tí òun náà jẹ Onigede ìlú Igede-Ekiti tó sì pẹ́ lórí àpèrè kó tó wàjà.
Ìlú Igede-Ekiti ni oríkò ìjọba ìbílẹ̀ Irepodun/Ifelodun ní ìpínlẹ̀ Ekiti.
Ọba Sikiru Adetona – Awùjalẹ̀ ilẹ̀ Ijẹbu
Ní ọjọ́ Kẹwàá, oṣù Karùn-ún, ọdún 1934 ni wọ́n bí Ọba Sikiru Adetona, Awùjalẹ̀ ilẹ̀ Ijebu ní Ijẹbu Ode, ìpínlẹ̀ Ogun sínú ìdílé oyè Anikinaiya.
Ọdún 1960 ni Ọba Adetona jẹ Awùjalẹ̀ ilẹ̀ Ijẹbu, èyí tó túmọ̀ sí pé ó ti lo ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́ta lórí ipò Awùjalẹ̀ ilẹ̀ Ijẹbu.
Bàbá rẹ̀ náà ti fìgbà kan jẹ Awùjalẹ̀ ilẹ̀ Ijẹbu láàárín ọdún 1895 sí ọdún 1906.
Ọba Adetọna wà lára àwọn ọba tí ẹ̀mí wọn gùn lórí àpèrè baba wọn.
Ọba Olofinlade Afunbiowo Ojijigogun Asodeboyede Adesida Kìíní ni Deji ti ìlú Akure, ìpínlẹ̀ Ondo láàárín ọdún 1897 sí ọdún 1957.
Ọgọ́ta ọdún ni Ọba náà lòláyé èyí tó mú jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọba Yorùbá tí ẹ̀mí wọn gùn púpọ̀ lórí ilẹ̀ baba wọn.
Àkọ́ọ́lẹ̀ ní ọdún 1860 ni wọ́n bí ọba náà sáyé àmọ́ àwọn ìròyìn kan sọ pé ó jú ọjọ́ orí tó ń lò náà lọ.
Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi III – Aláàfin ìlú Oyo
Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi Kẹta, Aláàfin ìlú Oyo, ìpínlẹ̀ Oyo jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọba ilẹ̀ Yorùbá tó gbajúmọ̀ púpọ̀ nígbà ayé rẹ̀.
Ní ọjọ́ Kẹẹ̀dógún, oṣù Kẹwàá ọdún 1938 ni wọ́n bí Aláàfin Adeyemi tó sì jáde láyé lọ́jọ́ Kejìlélógún, oṣù Kẹrin ọdún 2022.
Ìkú Bàbá Yèyé, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe máa ń pè é gorí àpèrè àwọn baba rẹ̀ ní ọjọ́ Kejìdínlógún, oṣù Kọkànlá ọdún 1970.
Ọdún méjìléláàdọ́ta ló lò lórí ipò gẹ́gẹ́ bí Aláàfin. Òun ni aláàfin tó pẹ́ jùlọ lórí ipò náà.
Ọba Adesoji Aderemi – Ọọni ilé Ifẹ̀
Ọba Titus Martins Adesoji Tadeniawo Aderemi Atobatele Kìíní jẹ Ọọni Ilé Ifẹ̀, ìpínlẹ̀ Osun láàárín ọdún 1930 sí ọdún 1980.
Àádọ́ta ọdún ni Ọọni yìí lò lórí ìtẹ́ àwọn bàbá rẹ̀.
Yàtọ̀ sí ipò ọba tí Ọọni Atobatele Kìíní yìí jẹ, ó tún ṣe gómìnà ẹkùn ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà láàárín ọdún 1960 sí 1962.
Ọba Atobatele tó jẹ Ọọni lẹ́yìn ìpapòdà ẹ̀gbọ́n rẹ̀ Ademiluyi Ajagun tó wà lórí ipò náà rèwàlẹ̀ àṣà.
Ọba Jimoh Oladunni Oyewunmi Ajagungbade III – Ogbomoso
Ọba Jimoh Oladunni Oyewunmi Ajagungbade Kẹta ni Ṣọun ìlú Ogbomoso, ìpínlẹ̀ Oyo láàárín ọdún 1973 sí ọdún 2021.
Ọjọ́ Kejìlá, oṣù Kejìlá ọdún 2021 ni Ọba náà jáde láyé lẹ́yìn tó lo ọdún mẹ́jìdínláàdọ́ta lórí ipò.
Ọba Ajagungbade Kẹta jẹ ọmọọmọ Ṣọun tó tẹ ìlú Ogbomoso dó, ìyẹn Sọun Ogunlola.
Onírúurú ohun ìdàgbàsókè ló wọ ìlú Ogbomoso nígbà ayé rẹ̀.