Àwọn Ọ̀ba aládé kórajọ ṣèpàdé pẹ̀lú Tinubu

Àwọn Ọ̀ba aládé kórajọ ṣèpàdé pẹ̀lú Tinubu

Fẹ́mi Akínṣọlá

Sultan ìlú Sokoto, Alhaji Muhammadu Saad Abubakar kẹta ti ní ẹrù tó wà lọ́rùn Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu báyìí kọjá sísọ pẹ̀lú gbogbo ìpèníjà tí Nàìjíríà ń kojú lọ́wọ́ yìí.

Lásìkò tí àwọn ọba aládé àti ọrùn ilẹ̀kẹ̀ ṣe ìpàdé pẹ̀lú Tinubu ní ilé ìjọba, Abuja lọ́jọ́ Ẹtì ni Sultan sọ ọ̀rọ̀ yìí.

Ní ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kẹsàn-án, oṣù Kẹfà ni Tinubu ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn lọ́balọ́ba ní gbogbo ẹkùn mẹ́fẹ́ẹ̀fà orílẹ̀ èdè yìí èyí tí Sultan ìlú Sokoto kó sòdí lọ sọ́dọ̀ Ààrẹ.

Alhaji Saad Abubakar sọ àrídájú rẹ̀ fún Ààrẹ pé gbogbo àtìlẹyìn àti ìrànlọ́wọ́ tó bá yẹ kí àwọn ṣe fún ìjọba ni àwọn ti ṣetán láti ṣe kí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lè tẹ̀ síwájú.

Ó ní gbogbo ìgbà tí Ààrẹ bá ti nílò àwọn ni àwọn ṣetán láti dáa lóhùn.

Ó fi kún pé àwọn ní ìgbàgbọ́ pé Nàìjíríà lábẹ́ ìdarí Tinubu yóò so èso rere fún àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè yìí.

Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀, Ooni Ile Ife, Oba Adeyeye Enitan Ogunwusi rọ Tinubu láti ṣe àmúlò àwọn lọ́balọ́ba fún àwọn ètò kọ̀ọ̀kan pàápàá nípa ètò ààbò.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here