Àwọn òṣèré kẹ́dùn pẹ̀lú Peju Ogunmola lórí ikú ọmọ rẹ̀

Àwọn òṣèré kẹ́dùn pẹ̀lú Peju Ogunmola lórí ikú ọmọ rẹ̀

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ádùrá kí á má fojú sunkún ọmọ ni gbogbo abiyamọ má a ń gbà sùgbón kò jọ pé ádùrá yìí gbà fún ìdílé àgbà òṣèrébìnrin, Peju Ogunmola, bí o ti pàdánù ọmọ rẹ̀ ọkùnrin kan ṣoṣo, Oluwanishola.

Alẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ kejì, oṣù kẹẹ̀sán án, ni ìròyìn ikú ọ̀dọ́mọkùnrin náà gba orí ayélujára.

Iroyin sọ pe, ọmọkunrin to di oloogbe ọhun nikan ni ọmọ to wa laarin Peju Ogunmola ati ọkọ rẹ ti oun naa jẹ agba oṣere, Sunday Omobolanle, ti ọpọ mọ si Papi Luwe.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ, Peju Ogunmola wa ni oko ere nigba ti iroyin iku ọmọ naa kan-an lara.
O ṣapejuwe iku oloogbe gẹgẹ bi adanu nla, to si gbadura pe ki Ọlọrun ko tu iya rẹ ninu.

Bakan naa ni oṣere mii, Odunlade Adekola ati Seun Oloketuyi, naa fi iroyin iku naa mulẹ. Amọ titi di asiko ti a ko iroyin yii jọ, a ko tii le fidi ohun to pa oloogbe naa mulẹ.

Oṣu diẹ sẹyin la gbọ pe Shola Omobolanle pari eto agunbanirọ rẹ.

Atẹjade kan ti adari ere, Seun Oloketuyi fi tufọ ọmọ naa lọjọ Iṣẹgun sọ pe ẹni ọdun mẹrinlelogun ni Shola Omobolanle ko to di pe o jade laye.

Ni ọjọ Kejila, oṣu ọdun yìí ni Sholaa Omobolanle ko ba ṣayẹyẹ ọjọ ibi rẹ mii to ba ṣi wa laye.

Shola Omobolanle jẹ akọrin takasufee ti irawọ rẹ ṣẹṣẹ n jade.
Ọpọ awọn gbajumọ oṣere lo ti n kọrin aro lẹyin ti ikede iku ọmọ kan ṣoṣo ti Peju Ogunmola bi Shola Omobolanle jade laye.

Agba oṣere, Jide Kosoko kọ soju opo Instagram rẹ pe eyi ko da rara, bawo ni a ṣe fẹ ṣalaye eyi… Sola Haaa

Adebayo Salami, ti ọpọ mọ si Oga Bello ni tirẹ sọ pe adanwo nla ni iṣẹlẹ naa to si jẹ asiko atironu. Oga Bello ni iru ọgbẹ ti iṣẹlẹ bi eyi maa n da si eeyan lọkan jẹ eyi ti kii jina rara.

O woye pe ko si ohun meji to ṣeeṣe ju ki eeyan gba fun Ọlọrun lọ nitori Oun ni ọba to mọ ohun gbogbo.

Femi Branch naa sọ pe ni kete ni iroyin naa kan oun lara ni oko ere ti oun wa ni ori bẹrẹ si ni fọ oun.

O ni “Anti mi, Ọlọrun nikan lo le tun yin ninu. Eleyii pọ ju, ko si obi to maa gbero iru nnkan bayii fun obi miiran. Ọlọrun a duro ti yin, a tu yin lọkan ma.”

Bakan naa ni Femi Adebayo juwe adanu ọhun bi eyi ti ko yẹ ki abiyamọ koju rẹ rara.

O kọ soju opo Instagram rẹ pe “lonii, a n ba ọkan lara awọn agba wa kẹdun, agba oṣere to n koju ọgbẹ ọkan ti ko yẹ ki iya kankan koju. Adura ati ero mi wa pẹlu yin ma. Ọlọrun Allah a fi si Aljannah Firdaus.”

Oṣere mii, Wunmi Toriola ninu atẹjade rẹ gbadura ki Ọlọrun tu Peju Ogunmola lọkan nitori ọfọ nla ni iṣẹlẹ naa jẹ.

Toyin Abraham sọ pe niṣe ni ọkan oun gbọgbẹ ti oun si n fi ifẹ ati adura ranṣẹ si Peju Ogunmola ni asiko yii.

Bukky Wright ninu ọrọ rẹ naa sọ pe ko si ọrọ kan ti eeyan le sọ lati fi juwe adanu yii. O ni oun n fi idile Ogunmola sinu ọkan.