Àwọn jàǹdùkú jí ẹrọ BVAS gbé ní ìpínlẹ̀ méjì- INEC
Ọrẹ Òtítọ́jù
Alága àjọ elétò ìdìbò ilẹ̀ wa (INEC), Mahmood Yakubu, ti ṣàlàyé àwọn àdojúkọ tí wọ́n rí lásìkò tí ètò ìdìbò ń lọ lọ́wọ́ yìí. Ó ní pẹlú gbogbo ètò àti ìpalẹ̀mọ́ tí àwọn ṣe ṣáájú àkókò yìí, ọkùnrin náà ní àwọn gídìgánńkú kan tí kò sẹ́ni tó mọ ibi tí wọ́n ti wá, tàbí èèyàn tó rán wọn, ti jí ẹ̀rọ BVAS, tí wọ́n fi ń ṣàyẹ̀wò àwọn olùdìbò gbé lọ ní ìpínlẹ̀ Katsina àti Delta.
Yakubu sọrọ yìí níbi tí wọ́n ti ń ṣakojọ ìbò táwọn èèyàn dì nílùú Abuja lọjọ Àbámẹ́ta, Sátidé, ọjọ́ kọkandinlọgbọn, oṣù Kejì, ọdún yìí. Ó ní oríṣìíríṣìí idojukọ làwọn ti rí káàkiri orílẹ̀-èdè yìí, títí kan ọrọ̀ igbokegbodo ọkọ̀ tó ń kó àwọn ohun èèlò ìdìbò tí wọ́n ń ní ìjànbá àtàwọn mí-ín tí wọ́n kò tètè dé látàrí ohun kan tàbí ò mí- ìn, àti ọrọ̀ ètò ààbò lọ́lọ́kan-ò- jọ̀kan tí kò fara rọ.
Yakubu ni pupọ awọn agbegbe jake-jado orilẹ-ede yii, ni ẹrọ BVAS ọhun ti ṣiṣẹ daadaa, ati pe awọn ibi perete kan ni wọn ti ni idiwọ lori bo ṣe n ṣiṣẹ mọnamọna. O tun fi kun un pe lara awọn wahala mi-in tawọn tun ni ni bi awọn oṣiṣẹ eleto idibo ko ṣe ri ibudo idibo de si laago mẹjọ aabọ aarọ to yẹ ki wọn ti wa nibẹ, latari wahala mọto, pẹlu gbogbo igbiyanju tawọn ti ṣe lori ọrọ naa.
O tẹsiwaju pe ẹrọ BVAS meji ni wọn ji gbe sa lọ, lasiko ti wọn kọ lu ibudo idibo kan ni Oshimili, nipinlẹ Delta. Ṣugbọn o ni kiakia ni ajọ INEC ti fi ẹrọ meji mi-in rọpo, ti wọn si wa nnkan ṣe si ọrọ eto aabo, wọn si tun ri i daju pe ibo didi tun tẹsiwaju pada.
Bakan naa lọrọ tun ri nijọba ibilẹ Safana, nipinlẹ Katsina. Nibi tawọn janduku ti kọ lu awọn ibudo idibo kaakiri, ti wọn si ji ẹrọ BVAS mẹfa gbe lọ, amọ tawọn oṣiṣẹ eleto idibo ti wọn wa nibẹ lo awọn ẹrọ mi-in dipo eyi ti wọn ji gbe lọ, wọn wa nnkan ṣe sọrọ eto aabo lati pada bọ sipo, wọn si tun bẹrẹ si i dibo wọn lọ pada.
Awọn oṣiṣẹ eleto aabo ti ri mẹta gba ninu awọn ẹrọ BVAS ti wọn gbe lọ yii, mẹta mi-in ṣi wa lọwọ awọn ẹni ibi ẹda ọhun.
Yakubu sọ siwaju si i pe ki i ṣe ike ti wọn n ju beba ti wọn fi dibo si ni wọn tori ẹ wa, bi ko ṣe ẹrọ BVAS yẹn gangan lohun ti wọn foju sun. O loun nigbagbọ pe laarin akoko perete to ku ki eto idibo fi wa sopin, ohun gbogbo yoo lọ nirọwọ-rọsẹ lai fi ti gbogbo wahala tawọn ti n koju bọ ṣe.