Àwọn Gómìnà ilẹ̀ Yorùbá kò faramọ́ ìdásílẹ̀ ‘Yoruba Nation’
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé wọ́n ní èyí wùmí ò wù mí ò wù ọ́,ni kìí jẹ́ á pawọ́ pọ̀ fẹ́bìnrin,ní báyìí, àpapọ̀ ẹgbẹ́ àwọn Gómìnà ìpínlẹ̀ Yorùbá ‘South-West Governors Forum’ ti làwọn ò fara mọ́ ìpolongo kan táwọn alákatakítí kan n ṣe pé kí ẹ̀yà Yorùbá ó dá dúró, èyì tí wọ̀n n pè ní Yorùbá Nation. Ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kẹwàá, oṣù Kẹfà, ọdún 2024 yìí, ni àpapọ̀ ẹgbẹ́ ọ̀hún bẹnu àtẹ lu ìgbésẹ̀ àti èròngbà àwọn èèyàn ọhun ti wọn n ṣepolongo fún ìdásílẹ̀ orílẹ-èdè Yorùbá Nation báyìí. Pàápàá jù lọ, bí àwọn kan ṣe tún fẹẹ fipa gbajọba ní sẹkiteraiti ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, loṣu tó kọjá yìí.
A gbọ́ pé lẹ́yìn ìpàdé pàtàkì kan tó wáyé lọ́jọ́ Ajé ọsẹ yìí, láàrin gbogbo àwọn Gómìnà ilẹ̀ Yorùbá, tó wáyé ní Alausa, niluu Ikeja, ìpínlẹ̀ Èkó, ni wọ́n ti sọ pé kò gbọdọ̀ s’ohun tó ń jẹ́ Yorùbá Nation lorile-ede yìí nítorí pé, ọ̀kan ṣoṣo ni gbogbo wa pata lórílẹ̀-èdè yìí, ẹya Yoruba ko si le pin kuro lara orileede Naijiria rara. Ìpàdé ọhún tó gba àwọn Gómìnà náà tó wákàtí mẹrin ni wọ́n tún lo àkókò náà láti fi kẹdun Olóògbé Rótìmí Akeredolu tó jẹ́ olórí ẹgbẹ́ náà tẹlẹ kó tó ó kú.
Bákan náà ni wọ́n tún gboṣuba ńlá fún Gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo, Ọgbẹni Lucky Ayedetiwa, bo ṣe rí tikẹẹti ẹgbẹ́ APC to fi fẹẹ dupo Gómìnà ìpínlẹ̀ náà gbà lọwọ́ ẹgbẹ́.
Lára àwọn Gómìnà ilẹ̀ Yorùbá tí wọ́n peju-pesẹ síbi ìpàdé pàtàkì ọ̀hún ni: Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó, Babajide Sanwo-Olu, Gómìnà ìpínlẹ̀, Ondo, Lucky Ayedetiwa, Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde, Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke Jackson, Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun àti Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkìtì, Ọgbẹni Abiọdun Oyebanji.