Àwọn ẹgbẹ́ alátakò fẹ̀sùn màgòmágó, àṣìlò agbára, kan APC nínú àtúndì ìbò

Àwọn ẹgbẹ́ alátakò fẹ̀sùn màgòmágó, àṣìlò agbára, kan APC nínú àtúndì ìbò

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọn ní ẹni ọ̀rọ̀ dùn kìí dákẹ́ , kí ti ara rẹ̀ ó má ba à ba dákẹ́. Bí ó ti jẹ́ pé lóòótọ̀ ,ọjọ́ Àbámẹ́ta tó kọjá yìí ni àtúndì ìbò wáyé ní àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́tàlá àti ẹkùn ìdìbò mẹ́rìndínlógún lórílẹ̀èdè Nàìjíríà.

Bó sì ti lẹ̀ jẹ́ pé ìbò ọ̀hún ti parí, síbẹ̀,awuyewuye tó ti ẹ̀yìn rẹ̀ yọ kò tí ì tán lẹ́nu àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ nídìí òṣèlú.

Ninu esi ibo ti ajọ eleto idibo ilẹ wa, INEC, fi sita, o fi han pe APC bori ibo ni ẹkun idibo mejila, APGA bori ni ẹkun meji, PDP yege ni ẹkun kan, nigba ti NNPP naa yege ni ẹkun kan ṣoṣo.

Ṣugbọn o fẹrẹ jẹ pe kaakiri ipinlẹ ni awọn ẹgbẹ alatako ti bẹrẹ si i fi ẹhonu han lori esi idibo yii.

Ohun ti wọn n sọ ni pe APC lo agbara rẹ lati dena awọn ẹgbẹ yoku, wọn ni wọn lo ipa ninu ijọba awarawa ni wọn fi yege.
Ni ipinlẹ Ogun to jẹ ilẹ Yoruba, ẹgbẹ oṣelu PDP ati ADC ti i ṣe ẹgbẹ alatako ṣalaye ẹdun ọkan wọn .
Ọtunba Olufemi Soluade ni Alaga ẹgbẹ oṣelu ADC nipinlẹ Ogun.
Ẹgbẹ rẹ naa lẹtọọ lati kopa ninu atundi ibo to waye fun ẹkun idibo Remo, Ikenne ati Sagamu lọjọ Abamẹta ọhun.

Ṣugbọn gẹgẹ bi alaye ti Otunba Soluade ṣe fun akọroyin laaarọ ọjọ Aje, o ni oludijẹ fun ADC ko dibo.

O ni APC lo agbara sé e mọ́lé ni.

“A ti dibo, ibo ti wa, o ti lọ, ṣugbọn ko lọ daadaa rara.

“Ninu ijọba awarawa ti a ni a n ṣe yii, ko yẹ ko ri bẹẹ. Ko yẹ ko jẹ ẹgbẹ kan lo maa sọ pe ki awọn ẹgbẹ to ku ma ni alaafia, ti yoo di pe awọn ọmọ ẹgbẹ ko ni i le dibo.

” A ti kọ lẹta ṣaaju idibo pe a maa dibo, a ka gbogbo ibi ti a maa de. A kọ lẹta si kọmiṣanna ọlọpaa Ogun, wọn fi ranṣẹ si ti Remo, wọn ti n ṣiṣẹ ẹ lori ẹ ki wọn too sọ fun wọn pe ki wọn ma ṣe lẹta wa.

“Mi o ro pe ẹgbẹ oṣelu kankan wa to buru bii APC, niṣe ni wọn n fi ọkọ akọ́tamì le wa lọjọ ibo.

“Oludije ẹgbẹ oṣelu wa, Barrister Seyi Solomon Oso, ko le dibo, niṣe ni wọn di i mọle, wọn gbe mọto di ile rẹ pa, wọn ko jẹ ko jade dibo.

“Awon aworan ọta ibọn to wa niwaju ilẹ rẹ wa, mo le fi ranṣẹ si yin kẹ ẹ ri i .

“Bakan naa ni wọn gba gbogbo aga wa to wa nibi ti a ti fẹẹ dibo, iyẹn lo ku ọla ti a maa dibo.

“Ọlọpaa to to igba (200) ni wọn ko wa, wọn ni nnkan kan ko gbọdọ ṣẹlẹ nibudo ibo wa. Wọn ni APC nikan ni ibẹ wa fun, agidi la fi raye gba kọja

“Ṣe ibo ni wọn di ni ọjọ Satide yẹn? Ṣe ijọba awarawa la n ṣe yii abi a n tan ara wa?

“Awọn to n dari wa yii ko ni igbagbọ ninu ijọba awarawa, apaṣẹ-waa ni wọn.

“Ohun ti wọn fẹ́ ko ju ki wọn gba agbara ki wọn si maa ṣe nnkan to wu wọn, paapaa nipa owo araalu.

“Ohun t imo ri si i niyẹn, awon eleyii ki i ṣe oloṣelu, apaṣẹ- waa ni wọn.

“Ki odidi gomina maa lọ sibi ipolongo ibo, ko maa ni ,’ṣe ẹ mọ pe emi ni olori alaabo nipinlẹ yii, nnkan to ba wu yin ni kẹ́ ẹ ṣe ni Satide, tẹ ẹ ba ri wọn kẹ ẹ na wọn pa.”

“Mo fi eti ara mi gbọ eyi ni ipolongo ibo ni Ikenne, lọjọ kẹtala, oṣu Kẹjọ. Mo gbọ ọ.

“Kawọn eeyan maa dibo, kẹ ẹ maa na wọn, pe ti wọn ko ba ti le dibo fun APC, ki wọn maa lọ sile wọn.

“Ati éjẹ́ǹtì, à nà fẹ́ ẹ̀ ẹ́ kú, nnkan to ṣẹlẹ ni Satide niyẹn, ni Isara, Iperu, Sagamu, nnkan to ṣẹlẹ niyẹn, teeyan ba maa sọ otitọ.

“Mo le fi fọnran ohùn awọn ti wọn na nibudo ibo ranṣẹ si yin, awọn obinrin ati ọkunrin ti wọn n ke irora.Ṣe ibo wa? niyẹn.

“Bi wọn ba fẹẹ ṣe e daadaa, ẹ jẹ ki wọn ko iwe idibo ti wọn ka yẹn jade, ki wọn ṣe ayẹwo finni-finni si i, awọn ọmọ ita lo tẹka sibẹ, ki i ṣe awọn oludibo to fẹẹ dibo.

“Ṣugbọn ẹ maa ri wọn, wọn a maa jo kiri, awọn naa mọ pe awọn eeyan ko fẹran awọn.”

Bẹẹ ni Oloye Kayode Adebayo ṣalaye fun akọroyin.

Nigba ti a kan si Akọwe ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ogun, Ọmọọba Aderibigbe Tella, lati ṣalaye lori awọn ẹsun yii, ohun to sọ ni pe:

” Ko si igba kan ti APC ko faaye gba ẹnikẹni lati dibo, kaka bẹẹ gan-an, awọn ẹgbẹ alatako yii ni wọn ṣe oriṣiiriṣii, inu mi dẹ dun pe awọn agbofinro wa nikalẹ.

“Awọn ni wọn ka owo mọ lọwọ ti wọn n gbiyanju lati ra ibo, wọn mu awọn eeyan kan, awọn eeyan naa dẹ ṣi wa lọdọ wọn.

“Ibo yẹn lọ ni irọwọ-rọsẹ, kalulu lo ni anfaani lati de ibudo idibo rẹ, wọn dibo bo ṣe yẹ ki wọn dibo, ko si ohun to jọ ohun ti wọn n sọ yẹn.

“Bawo ni APC yoo ṣe ni ki ẹgbẹ alatako ma dibo, nigba ti kalulu ni anfaani si ibudo idibo rẹ, ahesọ ni.

“Gbogbo ẹ lati oke dele, emi o ri okodoro ọrọ kankan ninu ẹ. Ko sohun to jọ bẹẹ, ibo to farahan ni, a si ko akoyawọ.”

Bẹẹ ni Akọwe APC Ogun sọ nipa iṣẹlẹ naa, ṣugbọn awuyewuye lori ibo naa ṣi n tẹsiwaju.