Osere fiimu pataki, Eniola Badmus, ti so pe ko si aburu kan to n se oun to le ma je ki inu oun dun.
Dipo bee, o ni orisiirisii idi lo wa fun oun ki oun fi maa yo sese.
Lara awon eleyii ni pe, gege bi o ti so, awon eeyan nla nla, ti won nifon leekanna, ni oun n ba rin.
Bakan naa, o ni oun ko tawo na, ti awon ise ti oun n se si n mowo wole fun oun.
Eyi ni idahun to fun arakunrin kan to bii lori ero ayelujarawon, to ni ko jo pe inu re dun.