Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yarí lẹ́yìn tí Makinde yí orúkọ Poly Ìbàdàn padà

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yarí lẹ́yìn tí Makinde yí orúkọ Poly Ìbàdàn padà

Fẹ́mi Akínṣọlá

L’Ọ́jọ́bọ ni Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ṣeyi Mákindé, kéde pé ayípadà yóò bá orúkọ tí wọ́n ń pe ilé ẹ̀kọ́ ẹ̀kọ́ gíga gbogbonìṣe Poly Ibadan, tí yóó sì di ilé ẹ̀kọ́ gíga gbogbonìṣe ‘Omololu Olunloyo’.

Ninu ọrọ ti Makinde sọ nibi ayẹyẹ ikẹyin ti ijọba ipinlẹ Ọyọ ṣe fun gomina tẹlẹri n’ipinlẹ naa, o kede pe ayipada orukọ ile ẹkọ giga naa waye ni iranti Oloogbe Victor Omololu Olunloyo.

Lara awọn eredi ti ọpọ eeyan ro pe o mu Makinde gbe igbesẹ naa ni boya nitori pe Olunloyo ni Giwa agba akọkọ to ṣe akoso ile ẹkọ giga naa l’ọdun 1970, ki o too tẹwọgba iṣakoso ipinlẹ Ọyọ fun oṣu meloo kan laarin ọjọ kinni, oṣu Kẹwaa si ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kejila ọdun 1983, gẹgẹ bi gomina.

Ṣugbọn ikede ti Gomina Makinde ṣe yii ko dun mọ awọn akẹkọọ kan ninu.
Agbarijọpọ ẹgbẹ awọn akẹkọọ, The Students’ Union Government (SUG) lo kọkọ kọ iwe ranṣẹ si Gomina Ṣeyi Makinde lẹyin to ṣe ikede naa l’Ọjọbọ.
Ninu atẹjade ti wọn fi ranṣẹ si awọn oniroyin lorukọ Alukoro ẹgbẹ naa, Akinade Ridwan Buniyamin, eleyii ti Aakọwe ẹgbẹ, Azeez Tolase, buwọlu, wọn bẹnu atẹ lu igbesẹ ti Makinde gbe.

Ẹgbẹ awọn akẹkọọ naa fi aidun inu wọn han, wọn si ṣapejuwe igbesẹ gomina pe, o fẹ ta ẹrẹ si aṣọ aala ati ami idanimọ ti ile ẹkọ giga naa ti ni lati nnkan bii ọdun mejilelaadọta sẹyin.

Ẹgbẹ naa ni awọn yoo ṣi ilẹkun anfaani silẹ fun asọyepọ pẹlu ijọba, gẹgẹ bi wọn ṣe n rọ Gomina Makinde lati yi ipinnu rẹ pada lori orukọ ile ẹkọ giga naa.

Wọn ni orukọ ti gbogbo aye ti mọ Poly Ibadan si naa ni awọn fẹ.
Yatọ si ẹgbẹ awọn akẹkọọ to kọ iwe ranṣe si Gomina Makinde nitori ayipada orukọ ile ẹkọ wọn, ẹgbẹ awọn akẹkọọ to ti kẹkọọ jade nile ẹkọ giga naa, ‘Ex-students and alumni of The Polytechnic, Ibadan,’ naa ke si Gomina Makinde pe ki o ma gbe igbesẹ ti yoo tabuku aṣẹyọri ti ọgọrọ awọn eeyan to kẹkọọ jade ni Poly Ibadan ti ṣe.

Aṣoju ẹgbẹ naa to jẹ akẹkọọ tẹlẹri ni Poly Ibadan, Ọmọwe Ismail Adewoyin to buwọlu lẹta ti wọn kọ ranṣẹ si Gomina Makinde, ṣalaye pe ifẹhonuhan awọn fi ara pẹ eyi ti awọn akẹkọọ Fasiti ilu Eko ṣe l’ọdun 2014, nigba ti ijọba fẹẹ yi orukọ ile ẹkọ naa pada si orukọ Oloye M.K.O Abiola.

O rọ Gomina Makinde lati wa awọn ọna mii ti wọn fi le bu ọla fun Oloogbe Ọmọlolu Olunlọyọ, dipo ayipada orukọ ile ẹkọ giga gbogboniṣe Poly Ibadan, nitori igbesẹ naa yoo mu ki ayipada ba orukọ to n bẹ lori iwe ẹri ti gbogbo awọn akẹkọọ tẹlẹri gba nile ẹkọ giga naa.

Ọrọ ti pupọ ninu awọn akẹkọọ Poly Ibadan ti akọroyin wa ba sọrọ fi lede naa ni pe, orukọ ile ẹkọ naa ki i ṣe orukọ lasan, nitori iyi to n bẹ ninu orukọ Poly Ibadan lo n fun gbogbo awọn ni iwuri.