Àwọn àjọ kan rọ Broda Shaggi láti dá àwọn èwe padà sí ìtàn àlọ́ lórísìírísìí
Láti ọwọ́ Yínká Àlàbí
Ajọ Goggle ati Slum2School Africa ti parọwa si ilumọọka adẹrin-posonu Broda Shaggi, pẹlu Falz ati Layi Wasabi nipa akanse isẹ to maa da awọn akẹkọọ alakọọbẹrẹ si awọn eto Eko alọ apamọ ati apagbe.
Ki wọn si bẹrẹ si ni lo ọwọ wọn lati maa fi kun nnkan nipa bibẹrẹ pẹlu kereyọọnu.
Gẹgẹ bi Otto Orondaam, to jẹ oludasilẹ Slum2School Africa se salaye.
O ni eto ẹkọ ti bẹrẹ ki o to di pe awọn ọmọ de ile iwe nipa awọn itan akọnilọgbọn ti wọn ti maa gbọ nile lorisiirisii.
O tẹ siwaju nipa sisalaye pe awọn ẹko yii lo n sọ bi a se jẹ ni eyi ti ọmọ ti maa nimọ nipa rẹ ko to bẹrẹ ile-iwe.
Apero yii waye ni Slum2School Innovation Hub ni Lekki, ipinlẹ Eko.
Oludari Google West Africa, Ọgbẹni Olumide Balogun lo sisọ loju eegun apero naa nipa sisọ itan “Great Rivers of Nigeria”.
Alejo pataki ọjọ naa Nancy Isime ati Bisola Aiyeola pẹlu Balogun sọ itan “Walls of Benin ati Queen Moremi Ajasoro”.
Gbogbo ijokoo ọjọ naa n jẹ ki o ye awọn ewe pe asa wọn se e mu yangan nibi gbogbo.









