Àwọn agbẹjọrò tó pe INEC lẹjọ́ lórí Temporary Voter’s Card, TVC, sọ pé àìkójú òṣùwọ̀n INEC ni.

Àwọn agbẹjọrò tó pe INEC lẹjọ́ lórí Temporary Voter’s Card, TVC, sọ pé àìkójú òṣùwọ̀n INEC ni.

Fẹ́mi Akínṣọlá

Aṣojú àwọn agbẹjọ́rò ọ̀hún, Victor Opatola ṣàlàyé fún akọ̀ròyìn nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan pé INEC kùnà nínú ojúṣe rẹ̀, èyítí kò jẹ́ kí ọ̀pọ̀ aráàlú lè dìbò lọ́jọ́ ìdìbò.

Ọpatọla ni “ Èrèdí tí a ṣe pe INEC lẹ́jọ́ ni pé àwọn èèyàn kan ti ṣe gbogbo ohun tó yẹ lábẹ́ òfin láti le ní káàdì ìdìbò alálòpẹ́ wọn, PVC, àmọ́ INEC fún wọn ní TVC wọ́n si sọ pé ẹni tí kò bá ní PVC kò lè dìbò .”

“ Ìtumọ̀ eléyìí ni pé àwọn èèyàn náà kò le dìbò bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣe ohun gbogbo tó yẹ kí wọn ṣe lábẹ́ òfin.”

“Èrèdí rè é tí a fi lọ sílé ẹjọ́ nítorí àwọn èèyàn náà ti ṣe ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe gẹ́gẹ́ bíi ọmọ Nàìjíríà rere láti lè dìbò àmọ́ INEC ló kùnà láti fún wọn ní PVC.”
Ọpatọla ṣàlàyé pé ní wọ̀n ìgbà tí orúkọ, àwòrán àti ìka àwọn èèyàn náà ti wà lọ́dọ̀ ọ INEC, àjọ ọ̀hún kò lágbára láti sọ pé kí àwọn èèyàn náà ma.”

Gẹ́gẹ́ bíi àlàyé rẹ̀, TVC yìí lè ṣiṣẹ́ lọ́jọ́ ìdìbò nítorí ohun kan náà ló wà lórí BVAS àti ẹ̀rọ ‘card reader’ tí wọ́n ń lò tẹ́lẹ̀.

Ó parí ọrọ̀ rẹ̀ pé iṣẹ́ kan náà ni PCV àti TVC ń ṣe, kò sì yẹ kí INEC dẹ́kun ẹnikẹ́ni láti dìbò nítorí kò ní PVC níwọ̀n ìgbà tó ní TVC.

Ó fi kún un pé ẹ̀tọ́ ọ gbogbo ọmọ Nàìjíríà ni láti dìbò, níwọ̀n ìgbà tí irufẹ ẹni bẹ́ẹ̀ bá ti fi orúkọ sílẹ̀, tó sì ní káàdì TVC náà lọ́wọ́, ó yẹ kó dìbò.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here