Àwọn àgbẹ̀ fọnmú lórí ìgbésẹ̀ Ìjọba àpapọ̀ lórí oúnjẹ

Àwọn àgbẹ̀ fọnmú lórí ìgbésẹ̀ Ìjọba àpapọ̀ lórí oúnjẹ

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìjọba àpapọ̀ ti kéde àwọn ìgbésẹ̀ tuntun láti mú ìgbèrú bá ètò ọ̀gbìn Nàìjíríà lábẹ́ ètò ìṣèjọba Ààrẹ Bola Tinubu.

Ìgbésẹ̀ yìí ló wà lára àwọn ìlànà tí ìjọba ń gbé láti ri pé Nàìjíríà ṣe àmúlò àwọn ohun èlò tó ní láti máa pèsè oúnjẹ lọ́pọ̀ yanturu, tó sì tún máa jẹ́ àtúntò lẹ́ka ètò ọ̀gbìn àti ìdókoòwò sí àwọn ohun amáyédẹrùn ní Nàìjíríà.

Igbákejì Ààrẹ, Kashim Shettima ló kéde àwọn ìgbésẹ̀ tuntun yìí níbi ìpàdé ètò oúnjẹ àti ètò ọ̀gbìn ti àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé.

Shettima ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìpèníjà gbogbo àgbáyé ni ọ̀rọ̀ ebi jẹ́, Nàìjíríà gbọdọ̀ jí gììrì láti ri dájú pé ó mú ọ̀rọ̀ pípèsè oúnjẹ ní òkúnkúndùn nítorí ọjọ́ iwájú.

“Kò sí ohun tó máa ń so àwọn èèyàn pọ̀ jùlọ ni ebi, tó sì máa ń ṣe àfihàn ibi tí èèyàn bá kù sí. Ọ̀rọ̀ oúnjẹ kìí ṣe láti wà láyé nìkan, bíkòṣe ohun tó nííṣe pẹ̀lú ètò ààbò àgbáyé.”

Agbẹnusọ Shettima, Stanley Nkwocha tó fi kókó ìpàdé náà léde sọ pé Nàìjíríà ti ń gbìyànjú láti mú àdínkù bá àwọn oúnjẹ tí wọ́n ń kó wọlé láti ilẹ̀ òkèèrè, kí wọ́n sì àlékún bá oúnjẹ tí à ń pèsè lábẹ́nú.

Láti ìgbà tí ìjọba ti yọ ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù lọ́dún 2023 ni ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ ti lọ sókè ní Nàijíríà tí ohun gbogbo sì ti gbówó lórí ní Nàìjíríà
Gẹ́gẹ́ bí igbákejì ààrẹ ṣe sọ, ìgbésẹ̀ tuntun yìí yóò fi ààyè sílẹ̀ fún ìlànà ṣíṣe ìforúkọsílẹ̀ fún ilẹ̀ lọ́nà kan, fífún àwọn àgbẹ̀ ní ẹ̀yáwó, ṣíṣe ètò ọ̀gbìn ní aládàá ńlá àti ètò pípèsè omi láti mú kí àwọn èrè oko dàgbà.

Ó wòye pé Nàìjíríà ní ìkápá láti máa bu omi rin àwọn ilẹ̀ tó tó eékà mílíọ̀nù mẹ́ta ṣùgbọ́n tó jẹ́ pé ìdá mẹ́wàá ni wọ́n ń ṣe báyìí.

Ó ní tí ìpèsè omi fáwọn ilẹ̀ tó ṣe é gbin nǹkan oko le mú kí èrè oko tí Nàìjíríà ń pèsè lé ní ìlọpo mẹ́ta, tí yóò sì mú àdínkù bá gbígbé ara lé sáà kan kí ètò ọ̀gbìn tó wáyé.

Ó fi kun pé ìwòye mímú ìdàgbàsókè bá Nàìjíríà ti ọdún 2021 sí 2025 tó wà nílẹ̀ yóò mú èèyàn tó tó mílíọ̀nù márùndínlógójì kúrò nínú ìṣẹ́ àti òṣì, pèsè iṣẹ́ mílíọ̀nù mọ́kànlélógún fáwọn èèyàn ní ẹsẹ̀ kùkú, tí yóò sì ri ìpèsè oúnjẹ lọ́pọ̀ yanturu.

Bákan náà ló sọ àrídájú rẹ̀ fáwọn olùdókoòwò pé àwọn àtúntò tí ìjọba ń ṣe yìí, àjọṣepọ̀ láàárín àwọn iléeṣẹ́ aládàni àti ìjọba, lílo ìmọ̀ ẹ̀rọ lẹ́ka ètò ọ̀gbìn yóò mú kí Nàìjíríà dùn-ún ṣe okoòwò.

Ààrẹ ẹgbẹ́ àwọn àgbẹ̀ ní Nàìjíríà, Kabir Kebram rọ ìjọba àpapọ̀ láti ri pé àwọn ìgbésẹ̀ tí wọ́n kéde pé àwọn fẹ́ ṣe yìí ni wọ́n ṣe àmúṣẹ rẹ̀ bó ṣe yẹ nítorí ọ̀rọ̀ lásán kò lè mú àtúntò bá ìlú.

Kebram nínú ìròyìn iléeṣẹ́ The Punch sọ pé níní òye kò lè da nǹkankan àyàfi tí ìjọba bá ṣe àmúṣẹ àwọn ìgbésẹ̀ náà lọ́nà tó tọ́.

“Lóòótọ́ ló máa so èso rere tí ìjọba bá ṣe àmúṣẹ rẹ̀. Èèyàn lè ní àfojúsùn ṣùgbọ́n tí wọn kò bá ṣe àmúṣẹ rẹ̀, pàbo ló máa já sí, kò ní sí ààbọ̀ kankan lórí rẹ̀.

“A rọ igbákejì ààrẹ lórí àwọn ìlérí tí wọ́n ṣe, kí wọ́n sì tọpinpin rẹ̀ délẹ̀ láti ri dájú wọ́n ṣe àmúṣẹ rẹ̀ dáadáa.

Kebram ní tí ìjọba bá ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí, ó dá òun lójú pé ìyàtọ̀ máa bá ọ̀rọ̀ oúnjẹ ní Nàìjíríà.

Bákan náà ni alága ẹgbẹ́ Competitive African Rice Forum, Peter Dama ṣèkìlọ̀ fún ìjọba lórí kíkéde láì ní ṣe àmúṣẹ àwọn nǹkan tí wọ́n bá sọ.

Dama wòye pé láti ìgbà tí ìjọba ti kéde pé àwọn máa pèsè katakata fún àwọn àgbẹ̀, wọn ò tíì fún ẹnikẹ́ni tí àsìkò òjò sì ti ń lọ.

“Ìjọba le ṣe ìkéde ṣùgbọ́n tí àmúṣẹ rẹ̀ máa ń pẹ́. Mo gbàgbọ́ pé tí ìjọba bá ṣe ìkéde, àmúṣẹ ló yẹ kó tẹ̀le lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.”

Ẹgbẹ́ àwọn àgbẹ̀ alábọ́dé ti obìnrin ní Nàìjíríà, Small-Scale Women Farmers Organization bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn ìgbésẹ̀ tí ìjọba àpapọ̀ ń gbé lórí ètò ọ̀gbìn pé kò so èso rere pàápàá fáwọn obìnrin tó ń ṣiṣẹ́ ọ̀gbìn.

Akọ̀wé ẹgbẹ́ náà, Chinasa Asonye sọ pé gbogbo ìgbìyànjú tí ìjọba ní àwọn ń ṣe lórí ètò ọ̀gbìn ni kò ì tíì mú kí oúnjẹ pọ̀ nílùú.

Asonye ní gbogbo ètò pípèsè ẹ̀yáwó, pínpín àwọn ohun èlò, pípèsè ilẹ̀ fáwọn èèyàn tí ìjọba ń ṣe ni kò kan àwọn obìnrin.

“Ìdá kan nínú ìdá mẹ́ta ohun tí à ń bèèrè fún ni kò ì tíì wá sí ìmúṣẹ. Lẹ́yìn gbígbé àwọn ètò bíi Malabo, CADI àti WSHADA kalẹ̀, ṣé à ń ṣe àmúṣẹ ìdá kan nínú wọn?