Àwo̩n ènìyàn ń jowú e̩wà mi– KimOprah

Àwo̩n ènìyàn ń jowú e̩wà mi– KimOprah

Mary Fágbohùn

Olori ewa ati omole elegbon agba teleri,, Chinonso Opara, ti a mo kaakiri si KimOprah, ti so pe awon eniyan ma n fi igba gbogbo da oun lebi nitori pe oun rewa. Ninu iforowero kan pelu olootu eto kan, Hawa Magaji, o wi pe, “Awon eniyan n dami lebi fun idi to je isokuso julo. Bawo le se le maa fami laso nitori pe mo rewa? Igba miiran, awon eniyan ma n ko eyin awon ilumooka si ara won, won a maa da ikorira sile lai nidi.”

O tun safihan pe oun ni irewesi okan leyin ti oun kopa ninu BBN. O wi pe, “Aye mi ti je okan lara ore-ofe ati awon ibukun, nitori pe awon nkan ma n sele ti eniyan a si maa wo pe kilode. Mo ni irewesi okan gidi leyin ile elegbon agba. Mi o so eyi fun enikeni ri. Mo ni irewesi okan gidi, nitori pe leyin idije talorewa ju, mi o de ibi kankan.

Mo ro pe BBN yoo je iyato nitori pe kii se ibi irorun funmi. Awon eniyan gba mi nimoran pe ki n gbiyanju re wo nitori pe mo ti wa ni Eko o le ni odun kan ti mo si ti n gba aseye. Mo ranti pe mo ma n so fun Denrele Edun lati fun mi ni die lara gig to kere si owo re lo.”

KimOprah tun fikun n pe bi obinrin ti ko ni alatileyin ba to eniyan dagba bi ti iya oun to ran okowo oun lowo lati dagba. O wi pe, “Didagba labe obinrin ti ko ni alatileyin to si jafafa fun mi ni ogbon lati se okowo, ati ni aye lapapo. To ba ye ki eniyan se nkan, eniyan ye ko se funrare. Mi o ki n duro di igba ti eniyan ba se nkan fun mi; ma a se funra mi”.

 

 

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here