Atiku gba káàdì bíi ọmọ ẹgbẹ́ ADC àmọ́, ẹgbẹ́ ti pín sí méjì
Fẹ́mi Akínṣọlá
Igbákejì Ààrẹ Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ rí, Atiku Abubakar, ti gba káàdì ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú ADC èyí tó fi kéde pé òun ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ọ̀hún.
Atiku sọ pe ẹgbẹ alatako ṣẹsẹ bẹrẹ niyii lẹyin to gba kaadi naa ni wọọdu kinni ni Jada nipinlẹ Adamawa lanaa ọjọ Aje ọjọ kẹrinlelogun oṣu Kọkanla yii.
Igbakeji aarẹ tẹlẹ sọ pe, ni bayii toun ti gba kaadi ọmọ ẹgbẹ ADC, gbẹ naa ṣetan lati le ijọba ẹgbẹ oṣelu APC lọ.
Atiku wa rọ gbogbo awọn ọmọlẹyin rẹ kaakiri orilẹede lati forukọ silk pẹlu ẹgbẹ ADC.
Nigba to n ki Atiku kaabọ sinu ẹgbẹ oselu naa, alaga ẹgbẹ oṣelu ADC nipinlẹ Adamawa, Shehu Yohanna, sọ pe gbogbo ọmọ ẹgbẹ ADC ni yoo ṣe iforukọsilẹ wọn nipinlẹ naa, ni bayii ti Atiku ti gba kaadi tiẹ.
Yohanna tun rọ awọn eeyan, papaa julọ, awọn ọdọ atawọn obinrin lati darapọ mọ ẹgbẹ ADC.
Loṣu Keje to kọja ni Atiku fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ, lẹyin to ni ẹgbẹ naa ko tẹle awọn alakalẹ to fi le ilẹ mọ.
Atiku sọ nigba naa pe oun kuro ninu ẹgbẹ naa tori wọn o ri ede-ai-yede to waye ninu ẹgbẹ naa yanju.
Lara awọn eekan oṣelu mii to ti darapọ mọ ADC ni minisita fun igbokegbodo ọkọ tẹlẹ, Rotimi Amaechi ati oludije sipo aarẹ tẹlẹ fẹgbẹ oṣelu LP, Peter Obi.
Awọn yoku ni Gomina tẹlẹ ni ipinlẹ Kaduna, Nasir el-Rufai, Gomina tẹlẹ ni ipinlẹ Osun, Rauf Aregbesola ati alaga tẹlẹ fun ẹgbẹ APC, John Oyegun.
Igun Nafiu Bala ninu ẹgbẹ oṣelu ADC ti tako iforukọsilẹ Atiku gẹgẹ bii ọmo ẹgbẹ oṣelu naa.
Igun naa sọ pe awọn ko ri igbakaeji aarẹ Naijiria tẹlẹ gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ ADC.
Igun naa sọ eyi di mimọ ninu atẹjade kan ti adari eto iroyin ẹgbẹ ADC, Christopher Okechukwu, fi sita ninu Abuja.
Wọn ni eto iforukọsilẹ Atiku lodi sofin ẹgbẹ naa tori awọn eeyan ti olu ileeṣẹ ẹgbẹ ADC ko ri bii ọmọ ẹgbẹ lo ṣagbatẹru eto ọhun.
Igun naa ṣalaye ninu atẹjade to fi sita wi pe awọn to ṣagbatẹru eto iforukọsilẹ Atiku ko lagbara labẹ ofin ẹgbẹ lati ṣe bẹẹ.
”A ti rọ Atiku lati ṣe iforukọsilẹ rẹ pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ to jẹ ojulowo, amọ, ko tii ṣe eleyii.”
Igun Nafiu Bala fikun ọrọ rẹ pe o ṣee ṣe ki Atiku fẹ lo ọgbọn yii lati wa ninu ẹgbẹ ADC titi ti PDP yoo fi yanju aawọ to n lọ ninu ẹgbẹ naa tan.
Wọn fi da Atiku loju wi pe gbogbo nnkan to jẹ ẹtọ rẹ gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ ADC ni yoo gba, ni kete to ba ti tẹlẹ alakalẹ ẹgbẹ lori fifi orukọ silẹ.
Gbogbo eyi n ṣẹlẹ latari faakaja to n lọ lori ipo aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu ADC, awọn kan ko ri David Mark gẹgẹ bii olori ẹgbẹ naa.
Ọrọ yii si wa nile ẹjọ giga apapọ ilu Abuja lọwọ yii, eyi tawọn ọmọ ẹgbẹ kan ti sọ pe ki ile ẹjọ yanju ọrọ naa tan kawọn oloṣelu lati ẹgbẹ oṣelu mii to maa darapọ mọ ẹgbẹ naa.









