Atiku Abubakar dáwọ́kọ́ lórí èrò àti gba káàdì di èèkàn lẹ́gbẹ́ ADC

Atiku Abubakar 2011 President campaign Photo by www.mortenfauerby.dk ©mortenfauerby 2010 - all rights reserved

Atiku Abubakar dáwọ́kọ́ lórí èró àti gba káàdì di èèkàn lẹ́gbẹ́ ADC

Fẹ́mi Akínṣọlá

Awọn àgbà bọ̀,wọ́n ní èrò ni ọbẹ̀ ẹ gbẹ̀gìrì.
Igbákejì Ààrẹ àná tẹ́lẹ̀ Atiku Abubakar, ti dáwọ́kọ́ gbígba káàdì African Democratic
Congress (ADC). Ìpinnu yìí wáyé látàrí bí àwọn kan ṣe n gbé yípo ẹnu pé Ààrẹ nígbà kan rí Goodluck Jonathan lè darapọ̀ mọ́ ìdíje Ààrẹ ọdún 2027, lábẹ́ òṣèlú tó kórajọ d’ọ̀kan ADC.

Atiku, tó ṣẹ́ṣé káàsa rẹ̀
kúrò nínú òṣèlú Peoples Democratic Party (PDP) nípa ìṣòro abẹ́nu, ti ṣètò gbogbo láti ríi dájú pé ó darapọ̀ wọnú ẹgbẹ́ òṣèlú ADC.
Gbagbaduu àti gba káàdì yìí ni àwọn alákòóso ẹ̀gbẹ́ ṣètò láti ṣe ní ilé rẹ̀ ní Jada,ní ìpínlẹ̀ Adamawa.

Ní báyìí ,ayẹyẹ ìdarapọ̀ ọ̀hún tí wọ́n ṣètò rẹ̀ fún ọjọ́ kẹfà oṣù kẹjọ ni wọ́n ti so rọ̀ di ọjọ́ mìíràn títí láé.
Alága ẹgbẹ́ ADC ní ìpínlẹ̀ Adamawa, Sheu Yohana,sọ pé òhun tí bá

Àwọn alákóso ADC ti sọ pé ìjíròrò pẹ̀lú Jonathan nípa ìṣèjọba Ààrẹ ti ń lọ ní kíkankíkan.

Alákóso ADC ní Adamawa, Shehu Yohana, sọ pé ó bá Atiku sọrọ, tó sọ pé ó ti yí ìṣẹ̀lẹ̀ náà sí àárín August, bíótilẹ̀ jẹ́ pé kò tíí sí pàtó ọjọ́ . Yohana sọ pé kò dájú pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà lè wáyé títí di oṣù kẹsàán ọdún 2025, gẹ́gẹ́ bí Atiku ṣe ń dúró de àwọn gómìnà APC kan láti darapọ̀ mọ́ ADC.

Ìròyìn mìíràn sọ pé ìbẹ̀rùbojo Atiku, Peter Obi, àti ADC ti pọ̀ sí i, pẹ̀lú àníyàn pé ìṣèlú Obi ti nípa lórí ADC ní Gúúsù, tó lè fa ìṣòro lórí ìrètí Atiku. Alága gbogbogboò légbẹ́ òṣèlú ADC sọ pé bí nnkan ṣe n lọ báyìí, ìgbésẹ̀ náà lè mú kí Atiku padà sí ẹgbẹ́ òṣèlú Social Democratic Party.