ASUU tún ti gùnlé ìyanṣẹ́lódì ọlọ́sẹ̀ méjì
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì ti kéde ìgbésẹ̀ bíbẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì ọlọ́sẹ̀ méjì ní gbogbo ilé ẹ̀kọ́ gíga tó jẹ́ ti ìjọba bẹ̀rẹ̀ láti òní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹtàlá, oṣù Kẹwàá, ọdún 2025.
Ààrẹ àpapọ̀ fún ẹgbẹ́ ASUU, Ọ̀jọ̀gbọ́n Chris Piwuna ló kéde ìyanṣẹ́lódì náà níbi àpérò àwọn akọ̀ròyìn tó ṣe ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì ìlú Abuja lọ́jọ́ Àìkú.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Piwuna sọ pé kò sí ìgbésẹ̀ kan sàn-án láàárín ẹgbẹ́ náà àti ìjọba àpapọ̀ láti dáwọn dúró láti má gùnlé ìyanṣẹ́lódì tí wọ́n ti ń gbèrò náà.
Ó ní ìkìlọ̀ ọlọ́jọ̀ mẹ́rìnlá tí àwọn ti fi léde láti ọjọ́ Kejìdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹsàn-án, 2025 ni ọjọ́ ti lọ lórí rẹ̀ láì sí èsì kankan láti ọwọ́ àwọn aláṣẹ tí ọ̀rọ̀ náà kàn.
Ó ṣàlàyé pé gbogbo àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì tó jẹ́ ti ìjọba àpapọ̀ tí wọ́n ti ń ṣe ẹgbẹ́ ASUU ni àwọn ọmọ ẹgbẹ́ kò ti ní ṣiṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kétàlá, oṣù Kẹwàá.
Ó fi kun pé ìgbésẹ̀ náà ń wáyé lẹ́yìn tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ti fẹnukò níbi ìpàdé àwọn aláṣẹ ẹgbẹ́ tó wáyé láìpẹ́.
Ní ọjọ́ Kejìdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹsàn-án, ọdún 2025 ni ẹgbẹ́ ASUU ti fún ìjọba àpapọ̀ ní gbèdéke ọjọ́ mẹ́rìnlá láti dáhùn àwọn ìbéèrè àwọn tàbí kí àwọn bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì.
ASUU nínú àtẹ̀jáde kan lẹ́yìn ìpàdé ẹgbẹ́ náà fẹ̀sùn kan ìjọba àpapọ̀ pé wọn kò ṣe ohun tí àwọn ń fẹ́, tí wọ́n sì ń dẹ́yẹ sí àwọn àti pé gbogbo ìfẹnùkò tí àwọn ní ni kò so èso rere.
Ní oṣù Kẹjọ, ọdún 2025 ni àwọn ẹgbẹ́ ASUU ní ilé ẹ̀kọ́ ìjọba àpapọ̀ àti ti ìpínlẹ̀ ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn nínú ọgbà ilé ẹ̀kọ́ wọn láti fi rán ìjọba lẹtí láti dáhùn àwọn ìbéèrè tó ti wà láàárín fún ọjọ́ pípẹ́.
“Gbogbo ìwọ́de tí a ṣe ni kò so èso rere kankan. Ohun tó fojú hàn báyìí ni pé ìjọba àpapọ̀ àti ti ìpínlẹ̀ kò náání ètò ẹ̀kọ́ àti ìgbáyégbádùn àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga rárá,” ẹgbẹ́ ASUU sọ.
Ẹ̀wẹ̀, ìjọba àpapọ̀ ní ọjọ́rú, ọ̀sẹ̀ tó kọjá ti pàrọwà sí ASUU láti má gùnlé ìyanṣẹ́lódì tí wọ́n ń gbèrò náà.
Mínísítà fún ètò ẹ̀kọ́, Tunji Alausa sọ pé ìjọba àpapọ̀ ní ìfarajìn sí sísan gbogbo àjẹmọ́nú àwọn olùkọ́ náà tí ìjóba jẹ wọ́n.
Alausa sọ pé ìjọba àpapọ̀ ti ń bojú wo gbogbo àwọn ìbéèrè ẹgbẹ́ náà, tí wọ́n sì ti ń ṣe akitiyan láti jíròrò pẹ̀lú wọn lójúnà àti dènà wọn láti gùnlé ìyanṣẹ́lódì.
Ó ṣàlàyé pé ìjọba ti gbé ìgbìmọ̀ kan dìde tó máa jíròrò pẹ̀lú àwọn olùkọ́, àwọn tí kìí ṣe olùkọ́ ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga tó fi mọ́ ilé ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe àtàwọn ilé ẹ̀kọ́ olùkọ́ni.
Ó fi kun pé Ààrẹ Bola Tinubu ti fún àwọn ní ìdarí láti dènà ìyanṣẹ́lódì, kó má ba à sí ìdíwọ́ fún ètò ẹ̀kọ́ kankan.
Ṣùgbọ́n ààrẹ ASUU sọ pé ẹ̀bẹ̀ tí ìjọba àpapọ̀ ń bẹ àwọn nígbà tó ku ọjọ́ méjì tí àwọn máa bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì ti pẹ́ jù.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Pinuwa níbi ètò iléeṣẹ́ Channels TV lọ́jọ́rú tó kọjá sọ pé ìjọba kìí kọbi ara sí ìbéèrè àwọn àyàfi tí àwọn bá ti fẹ́ gùnlé ìyanṣẹ́lódì.
“Wọ́n pè wá sí ìpàdé ní ìpínlẹ̀ Sokoto, wọ́n dá ọ̀sẹ̀ mẹ́ta fún wa, tí a sì gbà àmọ́ a ò gbọ́ nǹkankan mọ́ títí di ìgbà tí a dúnkokò láti gùnlé ìyanṣẹ́lódì.
“Wọ́n ń bẹ̀ wá láti má gùnlé ìyanṣẹ́lódì. Ìfẹnùkò ọdún 2009 tí a ṣe pẹ̀lú ìjọba, a ò tíì rí àbọ̀ rẹ̀.”
Ààrẹ ASUU náà tẹnumọ pé àwọn máa gùnlé ìyanṣẹ́lódì gẹ́gẹ́ bí àwọn ṣe sọ àyàfi tí ìjọba bá gbé ìgbésẹ̀ lórí àwọn ìbéèrè àwọn.
Ní oṣù Keji, ọdún 2022, ni ẹgbẹ́ ASUU gùnlé ìyanṣẹ́lódì olóṣù kan láti fi ṣèkìlọ̀ fún ìjọba láti mú àdéhùn tí wọ́n ṣe fún ẹgbẹ́ náà ṣẹ.
Ààrẹ ẹgbẹ́ ASUU nígbà náà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Emmanuel Osodeke fi àtẹ̀jáde kan sórí ẹ̀rọ ayélujára Twitter rẹ̀ pé àwọn yóò gùnlé ìyanṣẹ́lódì ṣùgbọ́n ìfẹ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àwọn ṣe pàtàkì.
Ní ọjọ́ Kẹẹ̀dógún, oṣù Kọkànlá, ọdún 2021, ASUU fún ìjọba àpapọ̀ ní gbèdéke ọ̀sẹ̀ mẹ́ta láti dáhùn gbogbo ìbéèrè àwọn ṣùgbọ́n tí ìjọba kùnà láti ṣe.
Nígbà tó ń ikọ̀ ìròyìn BBC sọ̀rọ̀, ọ̀jọ̀gbọ́n Osodeke ní láti oṣù kìíní ọdún 2021 ní ìjọba àpapọ̀ ti ṣe àdéhùn fún àwọn ṣùgbọ́n tí wọn kò ṣe àmúṣẹ rẹ̀ títí inú oṣù kejìlá.
Ní ọdún 2020, oṣù mẹ́jọ ni ASUU fi yan iṣẹ́ lódì, ìyanṣẹ́lódì náà bẹ̀rẹ̀ nínú ọsù kẹta tó sì parí nínú oṣù kejìlá lẹ́yìn tí ìjọba àti ASUU tọwọ́bọ àdéhùn.
Lẹ́yìn èyí ni ìjọba kéde pé àwọn ti fún ASUU ní ọgbọ̀n bílíọ̀nù Náírà ṣùgbọ́n ASUU ní àwọn kò rí omira débi tí wọn yóò rí ẹ̀jẹ̀ títí di àsìkò yìí.
ASUU ní ìjọba kò ì tíì mú àdéhùn wọn ṣẹ.