Arábìnrin kan fi è̩sùn kan o̩ko̩ Toyin Abraham pé ó fún òun lóyún
Seunfúnmi Fágbohùn
Alaboyun kan ti fi e̩sun kan Kolawole Ajeyemi ti o je̩ o̩ko̩ oserebinrin Toyin Abraham wi pe oun ni o fun un loyun.
Gege bi o̩mo̩binrin yi se so̩, oun ati Ajeyemi ti pero lati jo̩ wa papo̩ ki o to di ti Toyin.
Ninu fo̩nran kan ti o n lo̩ kaakiri, o ni oun ti loyun fun o̩kunrin naa lati o̩dun me̩rin se̩yin, o fi kun un pe oun si ti n gbe oyun naa kiri lati igba naa.
O fi e̩sun kan an siwaju sii pe, awo̩n e̩ni e̩mi ti so̩ fun oun pe ayafi ti Kolawole ba pada so̩do̩ re̩ ki oun to le ri o̩mo̩ naa bi.