Aráàlú nílò ààbò, kì í ṣe àló̩ àpagbè – Atiku
Yínká Àlàbí
Àtíkù Abúbákar, adije dupo Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ti sọ fún Ààrẹ Bọ́lá Ahmed Tinubu pé ohun tí Nàìjíríà nílò ni ààbò, kì í ṣe àló apagbe.
Ó sọ èyí lẹ́yìn tí wọ́n gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ me̩rinlelogun tí wọ́n ji ní Ìpínlẹ̀ Kebbi sílẹ̀. Àtíkù tún dá lórí ọ̀rọ̀ tí agbẹnusọ Ààrẹ, Bayo Onanuga, sọ nípa bí a ṣe gba àwọn ọmọbìnrin náà tí wọ́n ji ní Oṣù kọkànlá ọjọ́ kejidinlogun, o̩dun 2025.
Atiku salaye pe –
Ọ̀rọ̀ Onanuga jẹ́ ìpinnu láti pa òótọ́ mọ́, kí wọ́n sì jẹ́ kó hàn bíi pé ìjọba ṣe ohun tí kò tọ́́ sí wí pé ó jẹ́ aṣeyọrí.
Gbigba àwọn tí a ji sílẹ̀ kì í ṣe ìgbà tí a fi ń yọ̀; ó jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó ń fi hàn pé àwọn ẹlẹ́gbẹ́ ọdaran ń ṣiṣẹ́ ní òmìnira, tí wọ́n sì ń bá ìjọba n sọrọ ní gbangba.
Bí DSS àti ologun bá lè tọ́pa àwọn ajinigbe lato gba awo̩n ti wo̩n ji gbe, kí ló dé tí wọ́n kò mú wọn tàbí pa wọn níbè̩?
Kí ló dé tí ìjọba fi ń yìn ara rẹ̀ pé wọ́n bá ọdaran sọrọ, dipo kí wọ́n mú wọn?
Àtíkù tun salaye pé ìjọba Tinubu ti jẹ́ kí àwọn ajinigbé di “ìjọba míì” tí wọ́n ń gba owó ìtanràn, tí wọ́n sì ń bọ̀ lọ láì ní ìfarapa.
Kò sí orílẹ̀-èdè tó ní ìmúlò tó dáa tí yóò yìn ara rẹ̀ pé wọ́n bá ajinigbé sọrọ nígbà tí wọ́n sọ pé wọ́n mọ ipo wọn.
Bí ohun tí Onanuga sọ bá jẹ́ òótọ́, kí wọ́n ṣe jẹ́ kí àwọn ajinigbé náà sá padà?
Bí kò bá sì jẹ́ òótọ́, ó túmọ̀ sí pé Onanuga ń purọ̀ láti bo ìṣìkà ìjọba.
Ní parí, Àtíkù sọ pé:
“Àwọn araalu nílò ààbò, kì í ṣe àló̩ àpagbè tàbí àpamò̩.”









