Ara ń fẹ́ ìsinmi
A kú ọjọ́ mélòó kan ẹ̀yin olólùfẹ́ ìwé ÌRÒYÌN ÒWÚRÒ. Gbogbo ile n kọ? Eledua a jẹ ki a ri tiwa se ni gbogbo igba. Nitori bi a se ni ilu le to, awọn eniyan n kọle bẹẹ ni wọn n ra mọto pẹlu ọpọlọpọ ariya kaakiri ilu.
Arojinlẹ toni, ọrọ ọlọrọ ni mo fẹ ki a fi se arikọgbọn nipa bi a ṣe n lo ara wa. Mo pe akọle naa ni “ara n fẹ isinmi”. Bayii ni Dokita naa se salaye ara rẹ –
Mo kuro nile ni aarọ, mo si salaye fun iyawo mi pe maa pada dele ni irọlẹ sugbọn ni igba ti mo maa wo aago nigba ti mo n bọ wale, aago mọkanla alẹ ti lu.
Bi mo ṣe n bọ wale ni ipe kan wọ ori aago mi pe ẹsẹ kan aya ẹsẹ kan ọrun ni ọdọmọdebinrin kan wa nigba ti baba agbaaye ọgọta ọdun fipa ba ọmọ naa lo.
Bayii ni mo yi ọwọ mọto mi pada si ile iwosan, mo wa lori itọju ọmọ naa titi di aago mẹrin idaji nigba ti ọdọmọdebinrin naa pada saye daadaa. Eyi mu ki n ni suuru di aago mẹfa idaji ki n to maa lọ si ile.
Inu mọto ni mo wa nile iwosan nigba ti mọto awọn ọlọpaa wọle ti wọn si ni awọn fẹ alaye kikun lori ipalara to se ọdọmọdebinrin naa.
Bi mo se pari pẹlu wọn ni ipe DPO wọle pe alaga adugbo ati agbẹjọro wọn ti wa ni ago ọlọpaa lati gba beeli baba agbaaya naa.
Mo sare pe iyawo mi pe ki o jọwọ ba mi ko awọn ọmọ lọ si ileewe, mo ni lati gba agọ ọlọpaa dele. Mo sare pe agbẹjoro mi ko pese iwe lati ma ṣe jẹ ki baba agbaaya naa lọ sile. Ki n to dele lọjọ naa di aago mẹrin irọlẹ.
Lati le jẹ obi gidi to nifẹẹ awọn ọmọ rẹ, mo gba ileewe wọn lọ lati lọ ko wọn wale.
Ibi ti mo mọ de ni pe mo ko awọn ọmọ dele, bi mo se di ero ile iwosan ko ye mi. Won ni mo dede subu ni wọn ba sare gbe mi lọ si ile iwosan. Mo wa ni ile iwosan fun ọṣẹ kan gbako bẹẹ ni mo wa nile f’osu kan.
Fun odidi osu kan yii, orisiirisii isoro ati aisan lo jẹyọ ti wọn si yanju wọn lai si mi nibẹ.
Laarin osu kan yii, ile aye ko parẹ nitori pe wọn ko ri mi. Awọn to n saarẹ n ri iwosan bẹẹ l’awọn to l’ẹjọ naa n yanju ara wọn lai ri mi.
Ẹyin alarojinlẹ IROYIN OWURỌ, mo lero pe ẹ n tẹle mi, o dara ki eniyan sa ipa rẹ lati ran aye lọwọ sugbọn ko dara ki eniyan pa ara rẹ lai pe ọjọ.
Ko si osisẹ kankan to le yanju isoro ileesẹ kankan. Ọlọrun nika lo le yanju isoro aye.
Ko si bi a se gbiyanju to, a ko le yanju isoro aye. Ẹ jẹ ki a ṣe gbogbo nnkan ni iwọn tuwọn si.
Ire o.









