APC tako Makinde lórí N63bn to fe fi se àtúnṣe ilé ìjọba

Makinde

Gomina Ipinle Oyo, Onimo Ero Seyi Makinde, ti se alaye bo se je pe owo to to ogota o le meta bilionu naira (N63bn) ni ijoba oun fe na lori atunse ile ijoba Government House to wa ni Agodi, Ibadan.

Lati ojo ti ijoba ti kede erongba naa ni awuyewuye ti n sele, tori iye owo naa ya awon eniyan lenu.

Gomina ti wa so pe bi owo ile okeere se won, to wa je ki gbogbo nnkan won gogo, lo je ki owo naa lo soke.

Ni bayii, egbe All Progressives Congress ni Ipinle Oyo ti tako Gomina naa, to n so pe inakuna ati ifowosofo ni Gomina Makinde fe gunle.

Ninu atejade kan ti abenugan egbe naa ni Ipinle Oyo, Ogbeni Olawale Sadare, gbe sita, o ni opo nnkan lo wa to n je ilu niya to ye ki ijoba naa o f’owo se.

O tun wa fi kun un pe ijoba Abiola Ajimobi ti se atuse lori ile ijoba naa ni 2017.