APC sọ ìdí tí alága àpapọ̀ ẹgbẹ́ nàá, Umar Ganduje, fi kọ́wè fi ipò sílẹ̀ láìrò tẹ́lẹ̀
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ẹgbẹ́ òṣèlú tó ń ṣe ìṣàkóso lọ́wọ́ ní Nàìjíríà, All Progressives Congress (APC) ti tan ìmọlẹ̀ sí ìdí tí alága àpapọ̀ ẹgbẹ́ wọn, Abdullahi Umar Ganduje, ṣe kọ̀wé fi ipò rẹ̀ sílẹ̀ ọ́ọ̀è láìrò tẹ́lẹ̀.
Ọjọ ti pẹ diẹ ti awọn eeyan kan ti n sọ pe, nnkan ko rọgbọ ninu ẹgbẹ naa, amọ ti alaga naa fi ọwọ rọ gbogbo ahesọ wọn sẹyin.
Oludari ikede ati ipolongo fun ẹgbẹ APC, Bala Ibrahim, sọ fun akọroyin pe, koko idi ti Ganduje sọ pe o mu oun kọwe fi ipo silẹ ni eto ilera.
O ni “Ganduje sọ pe ki wọn fun oun laaye lati kuro ni ipo alaga ẹgbẹ, ki oun le raaye mojuto ilera ara oun.”
Bala Ibrahim sọ pe “gbogbo ẹni to ba ti le ni ẹni aadọrin ọdun lọjọ ori, gbọdọ mojuto ilera wọn, ki wọn si maa fun ara ni isinmi.”
“Aarẹ ti tẹwọgba iwe ifiposilẹ Ganduje, bẹẹ naa si ni awọn ọmọ igbimọ oludari ẹgbẹ.
“Gbogbo eeyan lo gba pe ipinnu Ganduje jẹ eyi to dara, ti awọn si yọnda pe ko lọ ọ tọju ara rẹ, ti ẹgbẹ yoo si gbaju mọ ṣiṣe awọn nnkan ti yoo ro o lagbara, ati eyi ti yoo mu ko ṣe aṣeyọri ninu awọn idibo to n bọ.”
Ọgbẹni Bala Ibrahim tun sọ pe irọ patapata ni awọn iroyin to n lọ pe alaafia ko si ninu ẹgbẹ, paapaa nipa ikọwe fi ipo silẹ Ganduje.
O ni “ahesọ lasan ni iroyin ti eeyan ko ṣe iwadii lori rẹ ko to o gbe jade, ẹṣẹ si ni ki eeyan ma a ṣe gbọyi-sọyi.”
Agbẹnusọ fun ẹgbẹ oṣelu APC ni, “lori ọrọ ta ni yoo rọpo alaga to n lọ, ẹgbẹ ni iwe ofin to ṣalaye ilana bi wọn yoo ṣe yan eeyan lati ariwa tabi guusu.
“Eeyan to wa lati agbegbe ti alaga to kọwe fipo silẹ ti wa ni wọn gbọdọ yan ko jẹ adele titi eto idibo ẹgbẹ oṣelu yoo fi waye.”
O fikun ọrọ rẹ pe, “Alaga to n lọ, Ganduje, lo wa lati apa Ariwa, ti Bukar Dalori yoo si wa gẹgẹ adele fun ipo alaga titi a o fi yan alaga miiran ninu eto idibo.”
Abdullahi Umar Ganduje kọwe fipo silẹ lẹyin ọdun meji gẹgẹ bii alaga ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress.
Igbesẹ rẹ yii lo waye lẹyin ti rogbodiyan bẹ silẹ ni ọsẹ to kọja nibi ipade ẹgbẹ oṣelu APC ni Ariwa Naijiria.
Nibi ipade naa ni awọn ọmọ ẹgbẹ kan ti yari lori bi Aarẹ Tinubu ko ṣe kede igbakeji rẹ, Kashim Shettima, gẹgẹ bii ẹni ti wọn yoo jọ jade dupo gẹgẹ bii Aarẹ ati Igbakeji nibi eto idibo aarẹ odun 2027.
Abdullahi Umar ni wọn bi ni abule Ganduje nijọba ibilẹ Dawakin Tofa nipinlẹ Kano lọdun 1949.
O bẹrẹ si ni ka Kurani ati imọ nipa Islam ni abule ọhun, to si tun lọ si ile ẹkọ alakọbẹrẹ Dawakin Tofa lati ọdun 1956 si 1963.
Ganduje lọ si ile ẹkọ girama Birnin Kudu ni ọdun 1964, to si kẹkọ jade ni ọdun 1968.
Bakan naa lo tun lọ si ile ẹkọ fun awọn olukọ ni Kano laarin ọdun 1969 si 1972.
Gomina ana nipinlẹ Kano ni, o si gba oye imọ eto ẹkọ lati fasiti Ahmadu Bello, Zaria, nipinlẹ Kaduna ni ọdun 1975.
Ni ọdun 1979, o gba oye Masters lati ile ẹkọ fasiti Bayero, Kano, to si tun pada lọ si fasiti Ahmadu Bello ni ọdun 1984 si 1985 lati lọ kọ ẹkọ nipa ato ile, Public Administration.
O gba oye PhD lati fasiti ti ilu Ibadan ni ọdun 1993.
Ganduje darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu NPN lasiko ijọba alagbada keji, to si jẹ igbakeji abẹnugan ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kano lati ọdun 1979 si 1980.
O jade dupo fun ile igbimọ aṣofin kekere ni ọdun 1979 labẹ ẹgbẹ oṣelu NPN ṣugbọn o lulẹ.
Ni ọdun 1998, o darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP, to si gbiyanju lati gba tikẹẹti dupo gomina ṣugbọn lẹẹkansi o lulẹ sọwọ Rabi’u Musa Kwankwaso.
Ṣugbọn Ganduje wọle gẹgẹ bii igbakeji gomina fun Kwankwaso laarin ọdun 1999 si 2003.
Bakan naa ni wọn tun jọ jade dupo, ti wọn si wọle ni Kano laarin ọdun 2011 si 2015.
Ni ọdun 2015, Dr. Abdullahi Umar Ganduje wọle gẹgẹ bii Gomina ipinlẹ Knao, to si lo sa meji laarin ọdun 2015 si 2023.