Anthony Joshua ò ja ẹ̀sẹ́ mọ́ – Adedamola Joshua

Anthony Joshua ò ja ẹ̀sẹ́ mọ́ – Adedamola Joshua

Yínká Àlàbí

Ijamba mọto to sẹlẹ ni ọsẹ to kọja ni opopona marose Lagos/Ibadan ti ori ko Anthony Joshua abẹsẹ ku bi ojo yọ, ni eyi to mu ki ẹmi rẹ gbọn.
Ijamba mọto naa mu awọn ọrẹ bi ọmọ iya Anthony lọ. Awọn yii ni wọn jọ n sisẹ pọ ti wọn si n tọ Anthony sọna, awọn ni iku ti yọ ọwọ wọn lawo yii.
Isẹlẹ buruku yii lo bi ọkan Anthony ti ko papọ mọ, Ẹgbọn rẹ Adedamola ni ko si bi o se le pada si ibi ẹsẹ jija mọ. “ Tẹlẹ naa, inu fuu aya fuu ni gbogbo ọkan ẹbi ni awon ọjọ ti Anthony ba ti fẹ ja. Ori adura ni gbogbo wa maa n wa. O di igba to ba ja ewe olubori ki ọkan to balẹ. Fifi ija silẹ, ki o si lọ wa nnkan miiran se naa ni idunnu ẹbi. Ọrọ rẹ si ti da bi onirese to kọ ti ko fingba mọ, eyi to ti fin silẹ ko le parun”.
Adedamola ni Anthony ti seleri pe gbogbo iranlọwọ to ba yẹ loun maa se fun ẹbi Sina Ghami ati Latif Ayodele ti wọn ba isẹlẹ buruku naa lọ.
Egbọn Anthony salaye yii fun awọn oniwee iroyin Punch nigba ti wọn se abẹwo si awọn ẹbi Anthony Joshua ni Sagamu.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here