Àlàyé lórí ìdí tí Ààrẹ Togo fi lè wà nípò títí láí

Àlàyé lórí ìdí tí Ààrẹ Togo fi lè wà nípò títí láí

Fẹ́mi Akínṣọlá

Wọ́n ti búra wọlé fún adarí orílè-èdè Togo, Faure Gnassingbé, gẹ̀gẹ́ bíi “Ààrẹ ìgbìmò àwọn mínísítà” orile-ede náà.

Ipo tuntun yii lo ga julọ ninu gbogbo ipo ijọba lorilẹede ọhun bẹẹ ni ipo naa ko ni gbedeke tabi akoko ti saa ẹni to ba wa nipo ọhun yoo pari.

Igbese yii lo n waye lẹyin ti wọn ṣatunṣe si ofin ilẹ naa ninu eyii ti wọn ti wọgile idibo to n gbe ololuṣelu de ipo Aarẹ, ti wọn si yan iṣẹjọba ti awọn aṣofin nikan yoo ti yan maa adari wọn
Awọn ọmọ ẹgbẹ alatako orilẹede naa ti sọ pe igbesẹ ọhun ko ṣẹyin akitiyan ijọba lati ri daju pe Gnassingbé ko fi ipo silẹ lailai.

Lati ọdun mejidinlọgọta sẹyin ni mọlẹbi Gnassingbé ti wa lori alefa ijọba Togo ki oun naa to tun gori oye lọdun 2005 lẹyin ti baba rẹ, Gnassingbé Eyadéma gbe agbara fun lẹyin ti oun funra rẹ ti wa nipo Aarẹ fun nnkan bii ogoji ọdun.

Ṣaaju lawọn alẹnulọrọ lorilẹede ọhun ti kọkọ sọ pe iditọgbajọba lọna to ba ofin mu ni bi wọn ṣe ṣatunṣe si iwe ofin ilẹ naa.

Lẹyin awọn ọrọ ọhun ni Gnassingbé dẹwọ awọn igbesẹ kan to yẹ ko gbe amọ o papa tẹsiwaju lati gba ipo tuntun ti awọn aṣofin yan an si.

Itumọ eyii ni pe lọwọ yii, ko si agbara kankan lọwọ Aarẹ orilẹede naa, o si da bii igba ti wọn ba kan fi oye da eeyan lọla lasan ni.

Amọ awọn onimọ ti sọ pe agbara pupọ ni wọn gbe fun Gnassingbé ni bayii ti wọn fi jẹ Aarẹ igbimọ awọn minisita.

Ninu idibo ile igbimọ aṣofin to kọja, ẹgbẹ oṣelu rẹ, Union for the Republic, jawe olubori pẹlu aga 108 ninu apapọ aga 113 to wa ninu ile aṣofin ilẹ naa.

Ninu oṣu Keje ọdun yii ni eto idibo ijọba ibilẹ yoo tun waye ni Togo labẹ ofin tuntun yii.