Alao Malaika sín Portable ní gbẹ́rẹ́ ìpàkọ́ lórí jàgídíjàgan

Malaika

Bola Afolabi

Akorin fuji to fi ilu Eko se ibujokoo, Sule Alao Malaika, ti sin akorin onijangbon, Portable, ni gbere ipako lori bi a se n fi iwa pele se aye.

Malaika, eni to korin ‘O boju mi je Olorun’ gba Portable ni imoran nigba ti olomokunrin to korin ‘Zazzoo’ ba a lalejo.

Portable lo ki Malaika leyin ti Olorun yo o, ti ko di ero ewon.

Adajo kan ni Ipinle Ogun ti so pe Portable jebi esun ole jija ati ikolu omolakeji lona ifiyaje.

Sugbon won ni dipo ko lo si ewon, o le san owo itanran to je ogbon naira.

Eyi ni Portable sare san, ti inu re wa n dun sese.

Malaika ba a dupe, sugbon o kilo fun un pe ko ye se jagidijagan.

O ni bi alariya kan ba wa wa to n se laulau, awon aniyan gidi to le ba a dowo po maa sa jinna si i.

Ni pataki, o bun Portable ni ebun owo dola.