Akọrin ẹ̀mí to ṣekúpa ò̩ré̩bìnrin ni ilé e̩jó̩ ti dájó̩ ikú fún
Mary Fágbohùn
Ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Nasarawa tó fi ìlú Lafia ṣe ibùjókòó ti dájú ikú fún akọrin ẹ̀mí Oluwatimileyin Ajayi, fún ẹ̀sùn ṣíṣekúpa àgùnbánirọ̀, Salome Adaidu.
Ní Ọjọ́bọ̀, ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹfà ni Adájọ́ Simon Aboki tó gbọ́ ẹjọ́ náà ní kí wọ́n lọ yẹgi fún Ajayi títí ẹ̀mí yoo fi bọ́ lara rẹ̀.
Ilé ẹjọ́ náà ninu oro rẹ̀ fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, Ajayi jẹ̀bi ṣíṣekúpa Salome Adaidu tó sì tún kun òkú rẹ̀ wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ bi eni kun eran agbo èyí tó lòdì sí abala 221 ìwé òfin ìwà ọ̀daràn tí ẹ̀ka àríwá Nàìjíríà, tó sì jẹ́ pé ikú ni ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ náà.
Ṣáájú ni ìyá ọmọ náà salaye pé Salome ló ń ṣe ọkọ fún òun láti ìgbà tí bàbá rẹ̀ ti kú àti pé òun fẹ́ kí wọ́n ṣe ìdájọ́ òdodo lórí ikú rẹ̀.
Nigba tí ìgbẹ́jọ́ náà ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, Ajayi sọ fún ilé ẹjọ́ pé òun kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan òun.
Àkọ́bí ẹbí Adaidu, Patience Unekwuojo Adaidu sọ fún oniroyin pé òun mọ̀ pé kò sí nǹkan tó le dá ẹ̀mí àbúrò òun padà ṣùgbọ́n ohun tó dá òun lójú ni pé Timileyin náà máa jáde láyé lọ́jọ́ kan.
Patience sọ̀rọ̀ yìí lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ dájọ́ ikú fún Timileyin Ajayi.
Ṣáájú kí ẹjọ́ náà tó dé ilé ẹjọ́ ni Patience sọ pé Ajayi kìí ṣe ọ̀rẹ́kùnrin àbúrò òun nítorí kò sí ẹni tó mọ̀ ọ́n nínú ẹbí àwọn.
Gẹ́gẹ́ bí nǹkan tí Patience sọ, ó ní Salome láwọn èròǹgbà tó dára fún ọjọ́ iwájú rẹ̀ àti pé ọ̀gá rẹ̀ ní Nicon Insurance ṣẹ̀ṣẹ̀ fi sẹ́nu ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan lórí ayélujára èyí tó máa ń ṣe ní gbogbo ọjọ́ Àbámẹ́ta kí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó wáyé.
Ẹni ọdún mẹ́rìnlélógún, tó ń ṣe àgùnbánirọ̀ ní iléeṣẹ́ Nicon Insurance tó wà ní Abuja ni Salome Adaidu kó tó jáde láyé.
Òun ni ọmọ karùn-ún nínú ọmọ mẹ́fà táwọn òbí rẹ̀ bí.