Àkójọpọ̀ àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ níbi ọdún Ojude Oba 2025

Àkójọpọ̀ àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ níbi ọdún Ojude Oba 2025

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọdún Ojúde Ọba 2025 dùn yùngbà, bẹ́ẹ̀ ló mi ìgboro tìtì, kódà ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì ń sọ nípa rẹ̀ títí di òní ọjọ́ kẹsàn-án oṣù Kẹfà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ayẹyẹ náà ti wáyé láti ọjọ́ Àìkú tí í ṣe ọjọ́ kẹjọ oṣù yìí.

Ṣe ti oriṣiiriṣii aṣọ olowo iyebiye tawọn eeyan wọ nibi ọdun naa ni ki a sọ ni, abi tawọn ẹṣin ti wọn ṣe lẹṣọọ nibi ayẹyẹ naa?

Awọn eeyan jankan jankan to wa nibi ọdun ọhun nkọ? Kaakiri gbogbo agbaye lawọn eeyan ti wa fun ọdun Ojude Oba eyi to mi ilu Ijebu Ode titi.
Abajọ ti Gomina Dapo Abiodun ipinlẹ Ogun fi sọ pe Ojude Oba ti di ọja agbaye bayii.

Nigba ti gomina n sọrọ nibi eto naa lo tun sọ pe ijọba yoo wa nnkan ṣe si gbagede ti wọn maa n lo fun ọdun naa eyi ti ko gba ero mọ.