Akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ 227 ni wọ́n jígbé ní ilé ẹ̀kọ́ St Mary – Àjọ CAN
Fẹ́mi Akínṣọlá
Alága ẹgbẹ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Kristẹni, Christian Association of Nigeria, CAN tẹ̀ka ìpínlẹ̀ Niger, Ẹni ọ̀wọ̀ Bulus Dauwa Yohanna ti sọ pé èèyàn 227, tó fi mọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn olùkọ́ láwọn ajínigbé tó ṣe ìkọlù sí ilé ẹ̀kọ́ St Mary Catholic Schools, Papiri ní ìjọba ìbílẹ̀ Agwara ní ìpínlẹ̀ náà ni wọ́n jí gbé lọ.
Ẹni ọ̀wọ̀ Yohanna nínú àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ rẹ̀ Daniel Atori fi léde sọ pé òun ṣe àbẹ̀wò sí ilé ẹ̀kọ́ náà níbi tí òun ti ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn òbí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà.
Ó ní òun ṣe àrídájú rẹ̀ fáwọn òbí àwọn ọmọ náà pé àwọn ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìjọba àtàwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò láti ṣe àwárí àwọn ọmọ náà àti láti láti gbà wọ́n sílẹ̀ láyọ̀ àti àlááfíà.
“Nínú àkọ́sílẹ̀ tí a rí, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ 215 àtàwọn olùkọ́ 12 láwọn ajínigbé náà jí gbé lọ.”
Ó fi kun pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan móríbọ́ lásìkò ìkọlù ọ̀hún, tí àwọn òbí sì ti ń lọ mú àwọn ọmọ wọn nítorí wọ́n máa ti ilé ẹ̀kọ́ náà pa fún ìgbà kan ná.
Bákan náà ló rọ àwọn èèyàn láti ṣe sùúrù, kí wọ́n sì máa gbàdúrà fún ìtúsílẹ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà láìpẹ́ ọjọ́.









