Akẹ́kọ̀ọ́ 72 láàhámọ́, ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ takú ìwọ́de lẹ́nu ọ̀nà EFCC n‘Ibadan
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Fásitì Obafemi Awolowo ni ìlú Ilé Ife (OAU) ti kéde fún àjọ tó ń kojú ìwà àjẹbánu, EFCC, pé kó tú àwọn akẹgbé wọn méjìléláàdọ́rin tó wà ní àhámọ́ wọn.
Èyí wáyé lẹ́yìn tí àwọn òṣìṣéẹ àjọ náà yabo ibùgbé kan ti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fásitì wà ní ìta ọgbà iléẹ̀kọ́ ọ̀hún mọ́júmọ́ Ọjọ́rú.
Ní iwájú iléeṣẹ́ EFCC tó wà ní ìyágankú ní ìlú Ibadan ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yìí péjú sí, tí wọ́n sì fárígá pé àwọn kò ní kúrò àyàfi tí EFCC bá tú àwọn akẹgbẹ́ wọn tí wọ́n mú lọ́nà àìtọ́ sílẹ̀.
Ohun tí a gbọ́ ni pé ìfẹhónúhàn àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yìí bẹ̀rẹ̀ ní nǹkan bí aago mẹ́wàá àti pé ń ṣe làwọn òṣìṣẹ́ àjọ EFCC dúró wámú lẹ́nu ọ̀nà pẹ̀lú ìbọn, tí wọ́n sì sèdíwọ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà láti wọ inú ọgbà wọn, tí àwọn adarí àjọ EFCC sì kọ láti yọjú sí wọn.
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà fárígá pé ìwà yíyabo ibùgbé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lòdì sófin àti pé bí wọ́n bá tilẹ̀ fẹ́ ko àwọn akẹ́kọ̀ọ́, ojú mọmọ ló yẹ kí wọ́n wá, kìí ṣe òru dúdú.
Àwọn aláṣẹ Fásitì Obafemi Awolowo kò tí sọ nkankan lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà títí di àkókò tí ìròyìn yìí bọ́
sórí afẹ́fẹ́.
Ìròyìn Òwúrọ̀ gbọ́ pé Alukoro ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọyọ, Ọ̀gbẹ́ni Adewale Osifeso bá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà sọ̀rọ̀, tó sì ní kí wọ́n yan ogun akẹ́kọ̀ọ́ láàrin wọn, láti bá àwọn adarí àjọ EFCC ni gbólóhùn papọ̀.
Ìdí tí wọ́n fi fẹ́ ṣe ìpàdé ọ̀hún kò yé wa ṣùgbọ́n àwọn agbófinró àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ló jùmọ̀ wọlé láti fọ̀rọ̀ jomi tooro ọ̀rọ̀.
Àwọn akọ̀ròyìn kò láǹfàní láti wọlé kópa nínú ìpàdé náà àmọ́ gbogbo wọn ti jìjọ wọlé, tí ìrètí sì wà pé wọ́n yóó yanjú ọ̀rọ̀ lórí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó wà ní àhámọ́ náà.