Àjọ NAFDAC gbẹ́sẹ̀ lé ayédèrú òògùn ibà
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣe àwọn àgbà sọ pé bí èèyàn bá n yọ́ ilẹ̀ dá,ohun burúkú a máa yọ́ irú wọn ṣe.
Kò dín ní páálí ayédèrú òògùn ibà ọ̀rìnlénígba dín mẹ́ta (277) tí àjọ tó ń rí sí oúnjẹ àti oògùn lílò lórílẹ̀ èdè yìí, NAFDAC, ti rí gbà báyìí lọ́wọ́ àwọn èèyàn kan nílùú Èkó, iye owó rẹ̀ sì ju over ₦1.2 bílíọ̀nù lọ.
Gẹgẹ bi NAFDAC ṣe ṣalaye, ‘Malamal Forte’, ni orukọ ayederu oogun iba ti wọn gbẹsẹ le naa, ile ikẹrusi kan to wa ni Ilasa-Oshodi, nipinlẹ Eko ni wọn ni wọn ko obitibiti oogun naa si.
Bakan naa lo jẹ pe inu paali oogun miran ni wọn ko ayederu yii si.Diclofenac Potassium 50mg, ni orukọ to wa lara paali oogun naa ti wọn ko wọ Eko lọna eru lati ileeṣẹ apoogun kan, Shanxi Tianyuan, lorilẹede China.
Ni afikun ọna eru ti ayederu oogun iba naa gba wọ orilẹede yii,niṣe ni awọn to ko o wọle tun parọ pe awọn nnkan eelo onirin lo wa nibẹ ti wọn fi gbe e wọle.
Ọga agba ajọ NAFDAC, Ọjọgbọn Mojisola Adeyeye, ṣalaye pe ajọ naa ko ni i kuna ninu ojuṣe rẹ lati ri i pe gbogbo ohun to le ṣe akoba fun alaafia araalu ni awọn kapa .
O ni pẹlu iranlọwọ ileeṣẹ aarẹ ati ẹka ijọba to n ri si ilera araalu, awọn alayederu oogun ati nnkan jijẹ ko ni i rọna lọ.
Eyi ti wọn gbẹsẹ le yii naa si jẹ ọkan lara ojuṣe wọn lati ri i pe aabo to peye wa fun awọn ọmọ Naijiria lẹka ilera.
Ẹ o ranti pe iṣẹlẹ kiko ayederu oogun wọle si orilẹede yii ko ṣẹṣẹ maa waye, o si fẹrẹ ma si ọdun kan ti ajọ NAFDAC ko ni i kede rẹ pẹlu awọn to n ṣe ayederu nnkan mimu ati jijẹ pẹlu.
Yatọ si bi ọwọ ṣe n ba awọn to n ko ayederu oogun yii wọle, ohun kan ti awon awoye ọrọ ṣalaye pe o tun n jẹ ko waye ni bi awọn oogun to jẹ ojulowo paapaa ṣe wọn gidi.
Lasiko yii, lati ra oogun iba tabi oogun awọn ọmọde ti owo rẹ ki i saba wọn tẹlẹ ti di nnkan inira gidi, idi si ni pe ẹkunwo ti ba iye ti wọn n ta awọn ogun naa gan-an.
Bi ojulowo oogun ti wọn n ra lowo pọọku tẹlẹ ba si ti di ohun ti apa ko ka mọ fun araalu, eyi yoo jẹ anfaani fun awọn to n peelo iru oogun naa lọna ti ko ba ofin mu lati maa ṣe ayederu rẹ sita.
Awọn wọnyi yoo bẹrẹ si i po ohun to le ṣa ara ni ijamba pọ fun araalu, wọn yoo si maa ko o sinu ọra tabi paali ti araalu ti mọ tẹlẹ, wọn yoo maa ta a ni iye ti awọn eeyan n ra a tẹlẹ fun wọn.
Niwọn igba to si ti ṣoro gidi lati da ayederu mọ, ti awọn to n ra a paapaa ko si ni idi kan lati fura pe ki i ṣe eyi ti awọn n lo tẹlẹ, bẹẹ ni oogun ayederu naa yoo ṣe maa tan kalẹ, ti yoo si maa ko idaamu ba ilera awọn to ba lugbadi rẹ.
Ohun kan to daju ni pe ko si ilu kan ti awọn alayederu oogun, nnkan jijẹ ati mimu yii ko si lorilẹede yii, awọn miran si wa to jẹ wọn tun n fi owo ko o wọle lati oke okun ni.
Ile ita oogun:
Ajọ NAFDAC ti rọ awọn eeyan pe ki wọn ṣọra pẹlu ibi ti wọn ti n ra oogun.
Ajọ naa rọ awọn eeyan lati maa ra oogun nile ita oogun to forukọ silẹ pẹlu NAFDAC nikan.
NAFDAC ni awọn ṣọọbu ti ko forukọ silẹ pẹlu NAFDAC lo maa n saba ta ayederu oogun yii.
Iye ti wọn n ta oogun
Awọn ibi ti wọn ti n ta oogun ni ẹdinwo le jẹ ibi ti wọn ti n ta ayederu oogun.
Ajọ naa ṣalaye pe iru awọn ibi ita oogun bayii maa n ra oogun ni ẹdinwo lọwọ awọn to n ta ayederu oogun, ẹdinwo yii lo si maa n jẹ ki ọpọ eeyan lọ síbẹ lati ra oogun.
Idi miran ti iru awọn ṣọọbu yii fi n ta oogun ni ẹdinwo ni pe wọn kii sanwo ori.
Paali oogun:
NAFDAC tun rọ araalu lati maa kiyesi paali oogun ti wọn ba fẹ ra.
Ajọ naa ni lọpọ igba ayederu oogun lo maa n wa ninu paali oogun ti ko ba dun-un wo loju.
Bakan naa ni ajọ NAFDAC tun sọ pe bi wọn ṣe kọ orukọ sara paali naa maa n ṣafihan bo ya oogun ayederu lo wa ninu paali iru oogun bẹẹ.
Lọpọ igba ni aṣiṣe maa n wa ninu bi wọn ṣe kọ orukọ oogun sara paali.
Oorun oogun:
Awọn araalu ni lati ṣọra pẹlu awọn oogun to ba n run bi igbo tabi ọda.
Ajọ NAFDAC ni oogun ti ko ba ti run bi oogun ṣe maa n run le jẹ ayederu oogun.