Àjọ LASTMA dá sèríà fún àwọn aláìgbọràn LASTMAN, wọ́n mú mọ́tò ẹgbẹ̀rún méje
Yínká Àlàbí
Ajọ LASTMA (Lagos State Traffic Management Authority) se ibawi fun awọn kolọrọsi osisọ wọn. Awọn ofisa to sẹ si awọn ofin ni ọlọkan-o-jọkan. Orisiirisii ibawi ni onikaluku wọn gba, gẹgẹ bi ẹsẹ wọn.
Awọn kan gba fifa leti, awọn kan gba iwe enini, awọn kan gba iwe gbe le rẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ọga LASTMA. Ọgbeni Olalekan Bakare-Oki salaye yii ni ọjọ isinmi ọjọ kẹta osu kẹjọ ni ilu Eko. Ọga yii ni mọto ti ko din ni ẹgbẹrun meje (7,000) ni ajọ awọn fi ọwọ sinkun ofin mu fun onirunru ẹsẹ.
O ni imọ igbalode se iranlọwọ to pọ fun awọn ni ọlọkan-o-jọkan.
Ọgbẹni Olalekan-Oki ni orisiirisii idanilẹkọọ ni awọn osisẹ LASTMA n se nile ati ni ita. O ni aye ti di aye imọ igbalode, ti aye ba si n kigbe gbe gbee gbe ti eniyan ko ba ba wọn gbe, ẹyinkule oluwarẹ ni wọn maa gbee si.
Alagba yii ni imọ ẹrọ igbalode jẹ oun logun ni kete ti oun di olori ajọ naa, nitori pe ko ni mọgbọn dani ki awọn osisẹ LASTMA maa fi asọ ijọba wọ iya ija pẹlu ara ilu. O ni eyi si so eso rere fun ajọ naa nitori pe ọpọ mọto ni awọn maa n mu lai lee kiri.
Ọga yii ni bi aọn se ni idanilẹkọọ ọlọsọọsẹ ni awọn ni olosoosu bẹẹ ni ti ọdun kan gbako naa ko gbẹyin. Eyi ti o n jẹ ki isẹ rọrun fun awọn sii lojoojumọ.