Àjo̩ NEMA pàro̩wà fún àwo̩n ènìyàn láti kúrò ní bèbè odò báyìí

Àjo̩ NEMA pàro̩wà fún àwo̩n ènìyàn láti kúrò ní bèbè odò báyìí

Yínká Àlàbí

Ẹkun omi mẹmii ati dukia lọ ni ipinlẹ Bauchi ni eyi to mu ki ijọba ipinlẹ naa tete ko awọn ti ori ko yọ si awọn yara ikawe kan, awọn kan tilẹ yari pe yara ikawe naa ko le gba awọn ati ẹbi ni eyi ti o mu ki wọn si taku si alapa ile wọn ti ẹkun omi wo ku.
Ọsẹ to koja ni ọko oju omi lo sadede doju bolẹ ni ipinlẹ Adamawa, eyi si mu ki awọn alaabo omi tete ji giri si isẹ naa. Ojo bii wakati mẹfa to rọ lai duro lo fa ẹkun omi naa.
Awon ajo alaabo omi ni orileede yii, NEMA (National Emergency Management Agency) ti kede fun gbogbo awon to wa lagbegbe omi lati kuro bayii nitori ẹkun omi. Wọn ni ile ti ẹkun omi parẹ ni ipinlẹ Adamawa nikan le ni ẹgbẹta (600).
Koda alukooro ọlọpaa ipinlẹ naa SP Suleiman Nguroje ni awọn ko tii le sọ iye emi to sọnu sinu ẹkun omi naa nitori pe awọn ajọ alaabo omi si n sa oku kiri, bẹẹ si ni awọn ẹbi lọtun losi naa n wa awọn eniyan wọn.
Isẹlẹ buruku naa gbomije loji ọpọ eniyan paapaa julọ ni awọn adugbo bii ile olowo pọọku Shagari Low Cost ati Yolde Pate to wa ni ilu Yola.
Awọn ajọ NEMA si ti se ikilọ gidi fun awọn to n gbe ni agbegbe odo ni awọn ipinlẹ bii Anambra, Sokoto, Gombe, Edo, Ogun, Bayelsa ati awọn agbegbe wọn. Wọn ni ẹkun omi yii le ya de awọn agbegbe naa laipẹ ọjọ. Wọn ni oju koto idaminu to ba yẹ ki a ko, ki a tete koo ki omi to wa ọna fun ara rẹ.