Àìsí ìbálòpò̩ lásìkò yí yanjú ìsòro mi – TG Omori
Mary Fágbohùn
Gbajumo oludara fonran orin ni Naijiria, ThankGod Omori, ti a mo si TG Omori, ti so nipa ipinnu re lati para re mo kuro ninu ibalopo.
Oniforan orin naa so pe lati igba ti oun ti yan iparamo fun ibalopo, ilaji isoro oun ti yanju.
Loju opo X re, o kowe pe, “Lati igba ti mo ti yan iparamo fun ibalopo ilaji isoro mi ti yanju.”
E ranti pe laipe yi ni Tiwa Savage so di mimo pe oun ti paramo fun ibalopo lati bii odun meta.
O ni idi ti oun fi paramo naa ni pe oun ko ni ololufe, pe okan re kii da si ibalopo ayafi to ba wa ninu ibasepo ife.