Àgùntan kò je̩ lábe̩ Gè̩é̩sì ni ò̩ré̩ èmi àti Tiwa Savage – Ke̩mi Olunlo̩yo̩
Seunfúnmi Fágbohùn
Ako̩ro̩yin ati onise̩ isegun ni, Kemi Olunloyo, to so̩ro̩ lakootan lori idi ti o fi pinnu lati ma se ilara gbajumo̩ olorin ni, Tiwa Savage.
Nigba ti o n so̩ro̩ lori e̩ro̩ ayelujare, Kemi Olunloyo ni ibe̩re̩ pe̩pe̩ ilara re̩ nii se pe̩lu o̩ro̩ ti o jade pe olorin naa ni o n bo̩ oun.
Ge̩ge̩ bi Kemi ti se so̩, ko nireti wi pe Tiwa yoo dake̩ lori aheso̩ o̩ro̩ naa.
O nireti wi pe, Tiwa Savage yoo so̩ro̩, ti yoo si da gbogbo akiyesi naa danu.
Ninu ariyanjiyan re̩:
“TIWA O SE NNKANKAN FUN MI.
MI O BEERE FUN OHUNKOHUN.
MO KAN MUU GE̩GE̩ BI O̩RE̩ TI O KERE SI MI NI.
E̩ DAKE̩ ATI MA A SO̩ OHUN TI E̩ KO GBO̩.
LOOOTO̩! MO N BINU SI I NITORI WI PE O DAKE̩ NIGBA TI ADETOUN SO̩ PE TIWA SAVAGE NI O N BO̩ MI.
TIWA KO BO̩ MI O, KO FUN MI LOWO, BE̩E̩ NI MI O BEERE FUN UN”.