AGN dá òsèré tíátà Jerry Williams dúró lé̩nu isé̩ lórí àsìlò oògùn
Mary Fágbohùn
Actors Guild ti Naijiria, AGN, ti fun Jerry Williams ni idaduro lenu ise alailopin, lori pe o lowo ninu oogun oloro.
Aare egbe naa ni orile ede, Emeka Rollas, eni to kede eyi ninu oro to fi lede ni Ojobo, so pe AGN ti n so ilowosi Williams “ninu oogun oloro lati osu kejila odun to koja, titi di igba ti okere fi bori mo o lowo.”
O so pe ajo Guild ye ki o ti da Williams duro saaju akoko yi sugbon “ajo naa pinnu lati gba a laaye ki o gba itoju, eyi to ko lati se ni pupo igba.”
Rollas so pe AGN pada pinnu lati da a duro leyin ti won woye re pe “kii se pe o n se ipalara fun ara re nikan sugbon o tun n se ipalara fun awon osere tiata ti won jo n sere.”
Aare naa so pe Williams yoo wa ni idaduro lenu ise “titi di igba ti onisegun oyinbo to danto tabi awon onimo nipa bi a se le e mojuto oro asilo oogun ba so pe ara re ti bo sipo.”