Agbófinró pa ogunlọ́gọ̀ ajínigbé mọ bùba wọn ní Kwara

Agbófinró pa ogunlọ́gọ̀ ajínigbé mọ bùba wọn ní Kwara

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ètò ààbò ti ń padà bọ̀ sipò ní ìpínlẹ̀ Kwara báyìí bí àpapọ̀ àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ wa se kọlu ọ̀pọ̀ ibùba àwọn agbébọn ní ìpínlẹ̀ náà.

Gẹgẹbi atẹjade ti agbẹnusọ àgbà feto ìròyìn fun gomina Ipinlẹ Kwara, Rafiu Ajakaye fi léde, ọpọ ẹmi awọn ọdaran yii lo lọ lori ikọlu naa.

Ajakaye sọ pe ẹnikẹ́ni ko ti i le sọ boya awọn ikọ ológun ijọba padanu ẹmi wọn nínú ìkọlù náà tàbí bẹẹ kọ.

Tẹ o ba gbagbe, lọjọ Aiku ni awọn afurasi agbebọn ya wọ ilu Oke-Ọdẹ, ni ìjọba ibilẹ Ifelodun, wọn si pa eniyan mẹrinla to fi mọ, baalẹ agbegbe kan.
Atẹjade naa ka bayii:

“Apapọ ikọ ọmọ ogun lo gbena woju awọn agbebọn ni ibuba wọn to wa ni agbegbe Baba Sango ni alẹ ọjọ Aje.

Ni ibi ìkọlù yii ni ọpọ ẹmi awọn ọdaran yii ti sofo”

Ìkọlù awọn ọmọ ogun sáwọn agbébọn yii lo waye ni ọjọ keji ti iṣẹlẹ ipaniyan naa waye ni ilu Oke-Ọdẹ ni ọjọ Aiku.

Iroyin fihan pe, ikọlu si ibuba awọn ajinigbe yii waye ni aala ipinlẹ Kogi si ipinlẹ Kwara.

Atẹjade naa tẹsiwaju pe, “saaju ni ajọ ọmọ ogun ofurufu ti kede ikọlu lati ofurufu sori awọn ọdaran náà.

Eleyi to jẹ ibẹrẹ ọtun lati jẹ ibuba awọn agbebọn run.

“Ko tii si aridaju kankan boya awọn ikọ ijọba padanu ọmọ ogun kankan.”