Agbésùnmọ̀mí tó kọlu ṣọ́ọ̀ṣì ìlú Ọ̀wọ̀ ní àṣepọ̀ pẹ̀lú agbésùnmọ̀mí Al-Shaba – DSS

Agbésùnmọ̀mí tó kọlu ṣọ́ọ̀ṣì ìlú Ọ̀wọ̀ ní àṣepọ̀ pẹ̀lú agbésùnmọ̀mí Al-Shaba – DSS

Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní bí ilé kò bá kan ilé kìí sí àjóràn.
Iléeṣẹ́ àjọ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Naijiria, DSS, ti ké sí ilé ẹjọ́ gíga ìlú Àbújá kó kọ béèlì àwọn afurasí márùn-ún tó n jẹ́jọ́ ẹ̀sùn ìfẹ̀míṣòfò tó wáyé nílé ìjọsìn kátóíìkì kan nílùú Ọ̀wọ̀, ìpínlẹ̀ Òndó lọ́dún 2022.

Ninu atako DSS si beeli ti awọn afurasi naa bere fun, DSS ni awọn afurasi ọhun ni ibaṣepọ pẹlu ẹgbẹ agbesunmọmi Al-Shabab, wọn si le salọ ti wọn ba gba beeli wọn.

Orukọ awọn afurasi naa ni Idris Abdulmalik Omeiza, Al Qasim Idris, Jamiu Abdulmalik, Abdulhaleem Idris, ati Momoh Otuho Abubakar, ti ọjọ ori wọn jẹ lati ogun ọdun si ọdun mẹtadinlaadọta.

Ọjọ karun un, oṣu Kẹfa, ọdun 2022 ni awọn afurasi naa kọlu ile ijọsin St. Francis Xavier Catholic Church, to wa ni adugbo Owaluwa, niluu Owo
Ọjọ kọkanla, oṣu Kẹjọ ti a wa yii ni wọn kọkọ foju bale ẹjọ ilu Abuja lori ẹsun igbesunmọmi pẹlu nọmba FHC/ABJ/CR/301/2025.
DSS ni fifun wọn ni beeli yoo ṣakọba fu igbẹjọ to n lọ lọwọ, yoo si fi ẹmi awọn ti yoo jẹri tako wọn nile ẹjọ sinu ewu.

Gẹgẹ bii DSS ṣe sọ, “Anfani wa fun wọn lati salọ ti wọn ba fun wọn ni beeli latari ibaṣepọ wọn pẹlu ẹgbẹ agbesunmi Al-Shabab.

“Awọn ti wọn jọ lọwọ ninu ikọlu naa ti salọ, bẹẹ ni wọn n bojuto igbẹjọ yii timọtimọ ti wọn si ti n mura lati yọ awọn olujẹjọ kuro ni ahamọ ti wọn wa.”

Ajọ ọtẹlẹmuyẹ ọhun sọ siwaju si pe awọn akẹgbẹ wọn naa n mura lati dunkoko mọ awọn ẹlẹrii lọna ati doju ẹjọ ọhun bolẹ.

DSS sọ pe “Awọn ẹlẹrii wa ti sọ pe ẹru n ba awọn pe awọn akẹgbẹ awọn afurasi le ṣakọlu si wọn, awọn ko si ni yọju sile ẹjọ ayafi ti a ba fi ọkan wọn balẹ pe ko ni si ewu kankan fun wọn.

“A ti sẹtan lati ri pe igbẹjọ yii ko fi akoko ṣofo lori ẹsun ti a fi kan wọn.”

Ẹwẹ, awọn afurasi ko tii fi ẹri kankan kalẹ lati fi han pe wọn ni oniduro.

DSS ni “Yoo ṣe anfani fun idajọ ododo atawọn ẹlẹrin ijọba lati ma fun awọn afurasi ni beeli kankan.”
Agbẹjọro awọn afurasi ọhun, Abdullahi Mohammad, sọ fun ile ẹjọ pe lati ọdun 2022 ti ọwọ ofin ti tẹ awọn onibara oun ni wọn ti wa ni ahamọ, nitori naa, akoko ti to ki ile ẹjọ fun wọn ni beeli lati maa gba ile wọn wa sile ẹjọ fun igbẹjọ naa.

O ni awọn onibara oun ti ṣetan lati fa awọn oniduro kalẹ lati fi han pe wọn ko ni na papa bora ti ile ẹjọ naa ba fun wọn ni beeli.

Ṣugbọn agbẹjọro ijọba, Calistus Eze kọ jalẹ pe ile ẹjọ ko gbọdọ gba beeli wọn.

Lẹyin atotonu awọn agbẹjọro mejeji, adajọ sun igbẹjọ naa si ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹsan an, ọdun 2025 lati pinnu lori beeli ti wọn n bere fun.

Ẹwẹ, agbẹjọro ijọba tun rọ ile ẹjọ pe ko ma fi orukọ gbogbo awọn ẹlẹrii oun sinu awọn iwe ẹjọ naa ti ọpọ eeyan lanfani lati ri lọna ati daabo bo wọn.

Adajọ ti gba ibere naa wọle.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ọjọ karun un, oṣu Kẹfa, ọdun 2022 ni awọn afurasi naa kọlu ile ijọsin St. Francis Xavier Catholic Church, to wa ni adugbo Owaluwa, niluu Owo, nibi ti ẹmi eeyan to le ni ogoji ti sọnu, ti ọpọ awọn mii si farapa yanayana.