Agbálẹ̀ ilé ìwòsàn di onísòwò ọ̀pọ̀lọpọ̀ olubi ọmọdé jòjòló

Agbálẹ̀ ilé ìwòsàn di onísòwò ọ̀pọ̀lọpọ̀ olubi ọmọdé jòjòló

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà sọ pé bí èèyàn bá n yọ́ ilẹ̀ dá ohun burúkú a máa yọ́ irú wọn ṣe.
Bẹ́ẹ̀ ọjọ́ gbogbo ni ti olè, ọjọ kan péré ni ti olóhun.
Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ọ̀rọ̀ rí bí ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ti tẹ òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn kan tí wọ́n bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ olubi ọmọ nínú báàgì kan tó gbé dání.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní, ọwọ́ tẹ obìnrin náà, Rose Mnisi níbi tó ti ń wá oníbàárà fún àwọn olubi ọmọ tó gbé dání náà lẹ́yìn tí èèyàn kan ta àwọn lólobó.

Ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún wáyé ní ẹkùn ìlà oòrùn Mpumalanga ní orílẹ̀ èdè South Africa

“Nígbà tí a mú obìnrin náà, a bá àwọn olubi ọmọ púpọ̀ nínú àpò kan tó gbé dání. Ó jẹ́wọ́ fún wa pé agbálẹ̀ ilé ìwòsàn kan ní òun,” iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sọ nínú àtẹ̀jáde kan tí wọ́n fi léde.

Ní Ọjọ́bọ̀ ni obìnrin náà, ẹni ọdún mọ́kàndínlógójì, fojú ba ilé ẹjọ́ fẹ́sùn pé ó ní ẹ̀yà ara èèyàn lọ́wọ́ lọ́nà àìtọ́. Wọ́n ti gba àwọn olubi ọmọ náà, tí wọ́n sì ti lọ ṣe àyẹ̀wò wọn.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní afurasí náà ń wá ọkọ̀ ọ̀fẹ́ lọ sí agbègbè Nelspruit nígbà tí ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá tó ń wọ́de ní ìlú Lydenburg tí wọ́n tún máa ń pè ní Mashishing tẹ̀ ẹ́.

Ọlọ́pàá ní àwọn kò lè sọ pàtó iye olubi ọmọ tó wà nínú àpò tó gbé dání nígbà tí wọ́n nawọ́ gán an.

“A ti fi ẹ̀sùn tó tọ́ kàn-án tó sì jẹ́ pé ó ṣeéṣe kí ẹ̀sùn rẹ̀ tún lékún bí ìwádìí bá ṣe ń lọ,” iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sọ.

Ní oṣù tó ń bọ̀ ni ìrètí wà pé afurasí náà yóò tún fojú ba ilé ẹjọ́ fún ìgbẹ́jọ́ láti gba béèlì rẹ̀.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá kò sọ ohun tí wọ́n máa fi àwọn olubi ọmọ náà ṣe àmọ́ àwọn kan ní ìgbàgbọ́ pé jíjẹ olubi ọmọ máa ń mú kí omi ọmú jáde fún ẹni tó bá ń tọ ọmọ lọ́wọ́ tàbí jẹ́ kí obìnrin tètè padà sípò lẹ́yìn tó bá bímọ tán àmọ́ ìmọ̀ sáyẹ́ńsì kò ì tíì fi èyí múlẹ̀.

Ní South Africa, àwọn ìpànìyàn kan ni wọ́n fi orí rẹ̀ sọ lílo ẹ̀yà ara èèyàn fún àwọn oògùn ìbílẹ̀.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù yìí, oníṣẹ̀ṣe Mozambic kan fojú ba ilé ẹjọ́ nígbà tí wọ́n ká àwọn ẹ̀yà ara kan mọ lọ́wọ́ ní ìlú Tshwane.

Àwọn tó ń ṣe ìwádìí ní, ó ṣeéṣe kí àwọn ẹ̀yà ara tí wọ́n bá lọ́wọ́ oníṣègùn náà jẹ́ ti ọmọbìnrin kan tí wọ́n pa lọ́dún 2023, tí wọ́n sì yọ àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀ lọ.