Mary Seunfunmi
Osere ati olusefiimu Muyiwa Ademola ti toro aforiji ni gbangba lọwọ awon akegbe re kan lori bi ko se le pe won sibi afihan fiimu re to n bo, “ORI Rebirth” to waye laipe yi, ni ojo ketadinlogbon osu kerin odun yii.
Ó sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ jáde; o ní òun nìkan lo ni ẹ̀bi náà, to sì ń tọrọ aforijjì.
Ademola tenu mo o pe awon akegbe oun, agba ati kekere, se pataki ni irin ajo oun; bee oun si ka won si pupo.
O so lori ero alatagba: “E kaarọ, eyin ebi mi. Mo kan fẹ lati lo akoko yii lati tọrọ aforiji lọwọ awọn to yẹ ki n pe ṣugbọn ti mi o pe, paapaa awọn ẹlẹgbẹ mi, agba ati kekere. Ẹbi naa wa lọwọ mi. E jọwọ e dariji mi. Gbogbo nyin ṣe pataki fun mi ati irin-ajo mi. Mo moyi yin ni bayi ati nigba gbogbo.
“E ma binu simi. Afojudi ko o. E MA BINU?
“E ṣeun fun ifẹ ti e fi han yi. Mo moyi re pupo. Mo nife gbogbo yin. Afihan ORI rebirth loni! Yoo jade ni sinima ni ọjọ kinni osu karun.”
Aforiji oṣere naa wa lẹyin ti o dabi ẹni pe o ise po lorun re pẹlu awọn igbaradi fun afihan naa.
“ORI Rebirth” yoo wa ni awọn sinima lati ọjọ kinni osu karun-un.
Akoja onifiimu naa ni ni sinima.
Awon ololufe ati awon elegbe re si ti fesi pelu ife ti o po, eyi ti Ademola moriri.