Adeleke kàn ń gba oríyín fún àṣeyọrí Oyetola ni – APC Ọṣun
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressive Congress APC ìpínlẹ̀ Osun, ti fi ẹ̀sùn kan ìṣèjọba Ademola Adeleke pé kò dẹ̀kun láti gba oríyìn àwọn àṣeyọrí Gómìnà Gboyega Oyetola.
APC Osun ní kò bójúmu bí ìjọba Ademola Adeleke se dáwọ́ iṣẹ́ dúró lórí Fásitì Ilesha, èyí tí wọ́n ní Gómìnà tẹ́lẹ̀, Gboyega Oyetola ti parí gbogbo isẹ́ lórí Fásitì náà.
Alága fìdíhẹẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Tajudeen Lawal ló sọ eléyìí níbi ìpàdé kan tí wọ́n ṣe pẹ̀lú àwọn akọ̀ròyìn nílùú Òsogbo l’Ọjọru.
Lawal ní owó tó tó àádọ́rùn-ún bílíọ̀nù náírà ni ó wà ní àpò ìjọba nígbà tí Adeleke di Gómìnà l’óṣù mẹ́ta sẹ́yìn.
Kola Olabisi, agbẹnusọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC, to lọ sojú alága níbi ayẹyẹ ọgọ́rùn-un ọjọ́ gẹ́gẹ́ bíi Gómìnà tí Adeleke ṣe ni kò bójú mu rárá, àti pé aadọrun bílíọ̀nù náírà náà ni ìjọba Adeleke kò rí nawọ́ sí pé nǹkan báyìí ló fi se.
“Adeleke gba iṣẹ́ lọwọ́ àwọn elétò ìlera tó tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbàata níye nígbàtí tí ètò ìlera ṣì mẹ́hẹ ní ìpínlẹ̀ náà.
“Adeleke ń lo àwọn jàǹdùkú láti dunkookò mọ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC lásìkò tí ètò ìdìbò Ààrẹ àti ilé ìgbìmọ̀ wáyé.
Síbẹ̀, kò tíì sí èsì tí ìjọba Ademola Adeleke fọ sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí ẹgbẹ́ òṣèlú APC Osun lọ́ mọ́ ọ lẹ́sẹ̀ yìí.