Adeleke jáwé olúborí ipò gómìnà ẹgbẹ́ Accord

Adeleke jáwé olúborí ipò gómìnà ẹgbẹ́ Accord

Yínká Àlàbí

Lẹyin wakati mẹrindinlogun ti gomina ipinlẹ Ọṣun, Ademola Adeleke fi ẹgbẹ oselu PDP silẹ, o si darapọ mọ ẹgbẹ Accord, kia lo sare gba tikẹẹti ipo gomina ni eyi ti gbogbo ọna si la kedere fun un. O wọle bii ẹni pe wọn jọ bẹrẹ ẹgbẹ oselu naa ni.
Gomina Ademola Adeleke ko da nikan si lọ si ẹgbẹ naa, o lọ pẹlu igbakeji rẹ, Kola Adewusi ati awọn olutẹle rẹ to ku ni wọn jọ Kẹyẹ lọ si inu ẹgbẹ Accord.
Elder Ibe Thankgod to jẹ Alaga awọn to n yẹ iwe awọn to fẹ dije du ipo gomina wo salaye pe Adeleke wẹ, o yan kanin-kanin. Alaga yii ni osuwọn rẹ kun daadaa.
Bi gomina se gba iwe ẹri yiyege tan lo f’ẹmi imoore han si gbogbo ẹgbẹ, o si sadura pe Elledua a ti awọn lẹyin lati jawe olubori ninu idije ọdun to n bọ.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here