Adediwura yóò kópa nínú ‘O̩jó̩ Às̩à ní Canada
Mary Fágbohùn
Osere tiata, Adediwura Olanrewaju, onirawo ninu fiimu atelera lori oju awe, telenovela ti Showmax, Wura, ti setan lati kopa nibi ajodun Ojo Asa (Asa Day Festival) ti yoo waye ni Canada ni osu kewaa.
Eyi je abajade isapa re nibi ajodun Ayangalu ti won sese se ni Ile-Ife, ipinle Osun, nibi to ti je adajo ati sorosoro.
Irinajo to n bo lona naa iseyesi lati odo alapejo Ojo Asa ni Canada, Joel Oyatoye, ti a mo si Baba Asa.
Ayeye olodoodun naa ti won pe akole re ni, ‘Asa Day’, ni ASA Day, Inc. Canada, sagbekale re ni ajosepo pelu ijoba apapo Naijiria.
Oyatoye naa n satileyin fun awon to jawe olubori nibi ajodun Ilu Ayangalu (Ayangalu Drum Festival) ti won sese se koja ni Ile-Ife, ipinle Osun, lo si ibi eto naa ni Canada.
Nigba ti yoo fesi lori itesiwaju eto naa, Adediwura, eni to ko ipa Olumide, ti a mo si Cobra, ninu Wura, to si je adajo nibi idije ajodun Ayangalu naa, dupe lowo Oyatoye fun atileyin re fun irinajo to n bo lona naa.