Adájọ́ ní ọnà tó bá wu àjọ elétò ìdìbò ní wọ́n fi lè gbé èsì wọn jáde
Fẹ́mi Akínṣọlá
Pẹ̀lú bí ìdájọ ṣe ń lọ lọ́wọ́ lórí ẹsùn tí olùdíje ẹgbẹ́ Labour, Peter Obi, fi kan Ààrẹ Bọla Tinubu àti ẹgbẹ́ APC, tó fi mọ́ àjọ elétò ìdìbò, lórí ètò ìbò Ààrẹ tó wáyé nínú oṣù Kejì, ọdún yìí, ilé-ẹjọ́ tó ń gbọ́ awuyewuye lórí èsì ìdìbò náà ti sọ pé kò sí ọ̀rọ̀ nínú pé àjọ elétò ìdìbò ilẹ̀ wa kò gbé èsì àbájáde ètò ìdìbò náà sórí ẹ̀rọ alátagbà.
Ilé-ẹjọ́ ṣọ pé kò sí òfin tó kàn-ań nípá fún àjọ elétò ìdìbò láti gbé èsì ìdìbò náà jáde sórí afẹ́fẹ́, tàbí kí wọ́n máa ṣe àfihàn èsì ìdìbò láti ibùdó ìdìbò tí wọ́n ti ń dì í, tàbí sí orí ayélujára. Wọ́n ní àṣẹ àti agbára wà lọ́wọ́ àjọ elétò ìdìbò láti lo ọ̀nà tó bá wù wọ́n láti kó èsí ìdìbò jọ ní orílẹ-èdè Nàìjíríà.
Fún ìdí èyí, adájọ́ dá ẹjọ́ tí olùpẹ̀jọ́ pè lórí eléyìí nù. Wọ́n ní kò sọ́rọ̀ níbẹ̀.
Bẹ́ ò bá gbàgbé, lára àwọn ẹ̀sùn tí Peter Obi fi kan àjọ elétò ìdìbò nílé-ẹjọ́ náà ni bí wọ́n ṣe kọ̀ láti máa ṣàfihàn èsì ìdìbò náà bó ṣe n jáde láwọn ibùdó ìdìbò kọ̀ọ̀kan, tí wọ́n sì tún kọ̀ láti gbé èsì ìdìbò náà sórí ayélujára bó ṣe ń lọ sí gẹ́gẹ́ bí àjọ elétò ìdìbò ṣe ṣèlérí pé àwọn máa ṣe kó tóó di pé ètò ìdìbò náà wáyé.
Bákan náà ni ilé-ẹjọ́ kò gba ẹ̀rí èsì ìdìbò tó rí bálabàla tí Obi kó wá sí kóòtù gẹ́gẹ́ bíi ẹ̀rí, wọ́n ní kò so ó mọ́ ibùdó ìdìbò kankan pé àwọn ni wọ́n ni-ín, bẹ́ẹ̀ ni kò sì tún ṣe bẹ́ẹ̀ nínú àwọn ẹ̀rí tó so mọ́ ẹ̀sùn rẹ̀.