Àbájáde ìpàdé Alaska fún Trump, Putin àti Ukraine
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ohun tí a bá lẹ́nu àwọn àgbà ni pé, àgbà kìí fi àárọ̀ họ̀dí, kó má funfun.Ṣùgbọ́n kò jọ pé
ọ̀rọ̀ rí bẹ́ẹ̀ lórí ìpàdé Alaska tó wáyé láàárín Ààrẹ ilẹ America, Donald Trump àti ti Russia, Vladimir Putin, èyí tí gbogbo ayé ti rò omi ro iyẹfun lé lórí pé yóò jẹ kí ogun parí ni Ukraine,ṣùgbọ́n tí kò mú nǹkan kan jáde.
Idi ni pe awọn alagbara meji naa ko fi ẹnu ko si nnkan kan lẹyin ipade to waye lọjọ Ẹti naa.
Lẹyin ipade to fẹrẹ to wakati mẹta naa, awọn olori fi atẹjade le awọn akoroyin lọwọ, wọn ko si dahun ibeere kankan lọwọ wọn.
Ẹ jẹ ka ṣe agbeyẹwo itumọ ohun ti wọn ṣe yii fun America ati Russia, ati ohun ti yoo tun ṣẹlẹ bayii ninu ogun Ukraine.
“Bi ọrọ ko ba ti I yanju, ko ti i yanju naa ni.”
Donald Trump lo ti kọko sọ eyi nipa ipade naa.
Ọna kan si ni eyi lati jẹ kaye mọ pe ọrọ ogun naa ko ti so eso rere lẹyin ipade ọpọ wakati.
Aarẹ Trump sọ pe oun ati Vladimir Putin ṣe awọn aṣeyọri kan, ṣugbọn ko ṣe alaye kikun nipa awọn aṣeyọri ọhun, o fi i silẹ kaye maa foju inu wo o ni.
“A o ti i yanju ẹ.” Trump lo pada sọ bẹẹ ko too jade kuro ni yara ipade naa lai da ọgọrun-un akọroyin to wa nibẹ lohun ibeere kan ṣoṣo bo ti kere mọ.
Trump rin irin ajo to jinna to bẹẹ lati ṣepade ti ko mu nnkan kan wa , koda bi awọn eeyan America-Europe ati Ukraine ba fẹẹ dunnu tẹlẹ, ipade yii ko mu ireti tabi adehun kankan wa fun wọn.
Trump to fẹran ki wọn maa pe oun ni olulaja ko mu nnkan kan bọ ninu ipade Alaska .
Bakan naa ni ko jọ pe ipade miran yoo tun waye, eyi to yẹ ko kan Aarẹ Ukraine; Volodymyr Zelensky .
Niṣe ni Aarẹ Trump dakẹ bi Putin to ṣide ipade naa ṣe bẹrẹ ọrọ akọsọ.
Bo si ṣe jẹ pe ilẹ America ni Alaska to, ara Putin silé bii pe orilẹ baba rẹ lo wa ni.
O si da bii asiko “Russian America”, ki wọn too ta wọn fun America ni Senturi kọkandinlogun (19th Century).
Ibeere nla ti awọn akọroyin ko ri bi Trump lọjọ Ẹti naa ni pe boya yoo fi ofin rẹ tuntun ba Russia ja gẹgẹ bii ifiyajẹni.