Ààrẹ Tinubu gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí ìlú ò fararọ ní ìpínlẹ̀ Rivers

Ààrẹ Tinubu gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí ìlú ò fararọ ní ìpínlẹ̀ Rivers

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọjọ́ tí wọn ò dá ni kìí pé, bó ṣe jẹ́ pé ọjọ́ ló ń pẹ́, ìpàdé kìí jìnà.
Ààrẹ Nàìjíríà, Bola Tinubu ti kéde gbígbe ẹsẹ̀ kúrò lórí òfin ìlú ò fararọ tí wọ́n kéde ní ìpínlẹ̀ Rivers.

Ní ọjọ́rú, ọjọ́ Kẹtàdínlógún, oṣù Kẹsàn-án ní Ààrẹ náà.

Tinubu ní gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn ní ìpínlẹ̀ Rivers ni wọ́n ti so agbéjẹ́ mọ́wọ́, tí kò sì sí ìnílò láti túnbọ̀ máa tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìlú ò fararọ.

Ó ní èyí mú inú òun dùn, tó sì jẹ́ pé kò sí ìnílò láti tún tẹ̀síwájú pẹ̀lú òfin náà.

Ẹ ó rántí pé ni ọjọ́ Kejìdínlógún, oṣù Kẹta, ọdún 2025 ni Ààrẹ Bola Tinubu ti kéde ìlú ò fararọ ní ìpínlẹ̀ Rivers látàrí làásìgbò òṣèlú tó ń wáyé níbẹ̀
Tinubu ti wá ní kí Gómìnà Fubara, igbákejì rẹ̀, Ngozi Nma Odu àtàwọn aṣòfin ní ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ náà tó fi mọ́ olórí ilé, Martins Amaewhule padà sẹ́nu iṣẹ́ wọn láti ọjọ́ Kejìdínlógún, oṣù Kẹsàn-án, ọdún 2025.
Níbi ọ̀rọ̀ tí ààrẹ bá àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà sọ ní àṣálẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kejìdínlógún, oṣù Kẹta ló ti sọ̀rọ̀ náà.
Tinubu ní làásìgbò òṣèlú tó ń wáyé ní ìpínlẹ̀ náà láti bíi oṣù mélòó kan sẹ́yìn ń kọ òun lóminú.

Ó ní gbogbo ìgbìyànjú òun láti ri pé ìfaǹfà náà wá sópin ló já sí pàbó.

Lẹ́yìn tí ààrẹ kéde ìlú ò fararọ ní ìpínlẹ̀ náà ló ní kí gómìnà Siminalayi Fubara àti igbákejì rẹ̀, Ọ̀jọ̀gbọ́n Ngozi Odu lọ rọ́kún nílé fún oṣù mẹ́fà.

Bákan náà ló ní gbogbo àwọn tí wọ́n dìbò yàn sílé aṣòfin ìpìnlẹ́ náà lọ rọ́kún nílé lóṣù mẹ́fà.

Ààrẹ ní nǹkan ìbànújẹ́ ló jẹ́ pé ìjọba ìpínlẹ̀ Rivers wo ilé aṣòfin láti bíi ọdún kan àbọ̀, tí wọn kò sì rí nǹkankan ṣe si títí di àsìkò yìí.

Ó ní láti ìgbà tí wọ́n ti ń bá ara wọn fa ìfaǹfà ni kò tis í ìlọsíwájú kan gbòógì ní ìpínlẹ̀ náà nítorí wọn kò jẹ́ kí àwọn ará ìlú jẹ múkùndún ìjọba àwaarawa.

Ó ní òun kò lè máa wòran, gẹ́gẹ́ bí ààrẹ, kí nǹkan máa bàjẹ́ ní orílẹ̀ èdè òun, èyí ló sì mú òun láti tẹ̀lé ìwé òfin tó fi ààyè gba òun láti kéde ìlú ò fararọ.

Lẹ́yìn èyí ni Ààrẹ Tinubu yan Vice Admiral Ibokette Ibas ni láti máa ṣe àkóso ìpínlẹ̀ Rivers fún oṣù mẹ́fà náà.
Tinubu sọ pé kí òun tó kéde ìlú ò fararọ ní Rivers, níṣe ni títẹ òfin lójú mọ́lẹ̀ ti wáyé níbẹ̀.

Ó ní odidi oṣù méjìdínlógún ni Gómìnà náà fi wó ilé aṣòfin tí kò sì tun un kọ́ padà, tó sì jẹ́ pé kò ààrẹ kankan tí yóò máa wòran kí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ṣẹlẹ̀ láì gbé ìgbésẹ̀ lábẹ́ òfin láti fòpin si.

Ó ṣàlàyé pé òun mọ̀ nípa àwọn ẹjọ́ tó lé ní ogójì tí wọ́n pè tako òun ní àwọn ilé ẹjọ́ ní Abuja, Port Harcourt àti Yenegoa lórí pé òun kéde ìlú ò fararọ ní ìpínlẹ̀ Rivers.

“Bó ṣe yẹ kí ọ̀rọ̀ rí nìyẹn lábẹ́ ìṣèjọba àwaarawa. Àwọn ẹjọ́ kan ṣì wà nílé ẹjọ́ títí di àsìkò yìí.

“Yóò jẹ́ ìjákulẹ̀ fún mi gẹ́gẹ́ bí ààrẹ láti má ṣe ìkéde náà. Gbogbo àwọn tó yàn wá sípò ni wọ́n ń retí èrè ìṣèjọba àwaarawa.”

Ó fi kun pé inú òun dùn pé ìpínlẹ̀ Rivers ti ṣetán láti padà sí ìṣèjọba àwaarawa tí kò sì sí ìnílò láti sún òfin náà síwájú.

Bákan náà ló fi àkókò náà ṣe ìràntí fáwọn gómìnà àtàwọn ilé aṣòfin káàkiri Nàìjíríà láti máa rántí pé nígbà tí àlááfíà bá wà nínú ìlú ni wọ́n le ṣètò tí yóò mú ìrọ̀rùn bá àwọn aráàlú.