Ààrẹ Buhari ṣèfilọ́lẹ̀ pápákọ̀ ojú omi l‘Eko láti kó ọjà wọlé láti òkè òkun
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn àgbà bọ̀,wọ́n ní aríṣe láríkà, Ààrẹ Orílẹ̀ yìí, Muhammadu Buhari ti ṣe ìfilọ́lẹ̀ pápákọ̀ omi èyí tó tóbi jùlọ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ní ìpínlẹ̀ Eko ìyẹn “Lekki Deep Sea Port”.
Èròńgbà ìjọba ni láti pọkún ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà àti ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà láti pọkún owó tó ń wọlé lábélé.
Ní ọjọ́ Àìkú ni ọkọ̀ ojú omi tó kó ẹrù kọ́kọ́ balẹ̀ sí pápákọ̀ omi náà tí owó rẹ̀ tó bílíọ̀nù kan ààbọ̀ dọ́là ṣaájú ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀ tó wáyé lọ́jọ́ Ajé.
Ní agbègbè “Lekki Free Trade Zone”, ìpínlẹ̀ Eko ni pápákọ̀ omi náà wà.
Gómìnà Babjide Sanwo-Olu ní òun gbàgbọ́ pé pápákọ̀ omi náà yóò pèsè iṣẹ́ tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba fún àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Eko, tí yóò tún máa owó gọbọi fún orílẹ̀ Nàìjíríà.
Ní oṣù Kejìlá ọdún 2017 ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ kíkọ pápákọ̀ náà lẹ́yìn tí ìjọba àti iléeṣẹ́ “The Lekki Port Investment Holding” tọwọ́bọ àdéhùn ọlọ́dún márùndínláàdọ́ta.
Bákan náà ni èròńgbà wà pé pápákọ̀ omi láti fi kó ọjà wọ orílẹ̀ èdè yìí tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣí yìí yóò mú àdínkù bá ọ̀wọ́n gógó tó máa ń bá owó tí wọ́n fi ń kó ọjà wọlé.
Dele Ayemibo sọ fún akọ̀ròyìn pé òun rò ó wí pé ó yẹ kí wọ́n ti pèsè ọ̀nà ojú irin tàbí ọkọ̀ orí omi tí yóò máa gbé àwọn ọjà kúrò ní Eko láti mú àdínkù bá súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ̀.
Ayemibo kádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ó pọn dandan láti pèsè ọ̀nà tó pọ̀ tí ọjà yóò máa gbà jáde kí ohun náà má ba à ní súnkẹrẹ fàkẹrẹ tó máa ń wáyé ní ọ̀nà Apapa.