A ò bá ohun ìgbéṣùmọ̀mí lára Nnamdi Kanu -Ẹlẹ́rìí tí DSS pè
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ọ̀kan lára àwọn olùjẹ́rìí DSS lórí ẹjọ́ ẹni tó ń pè fún ìdásílẹ̀ orílẹ̀ èdè Biafra, Nnamdi Kanu ti sọ fún ilé ẹjọ́ pé àwọn kò bá nǹkankan tó níí ṣe pẹ̀lú ìgbéṣùmọ̀mí lọ́wọ́ rẹ̀ nígbà tí wọ́n lọ nawọ́ gan lọ́dún 2015.
Olùjẹ́rìí kan tó pé ara à rẹ ní AAA sọ èyí nígbà tó ń dáhùn ìbéèrè lọ́wọ́ agbẹjọ́rò Nnamdi Kanu, Kanu Agabi.
Ọ̀gbẹ́ni AAA ti ṣáájú sọ̀rọ̀ ní ọgbọ̀n ọjọ́, oṣù Kẹrin, ọdún 2025 tó sì ṣàlàyé bí wọ́n ṣe mú Nnamdi Kanu àti obìnrin kan ní ilé ìtura Golden Tulip Hotel tó wà ní ìpínlẹ̀ Eko.
Nígbà tí agbẹjọ́rò Nnamdi Kanu ń bèèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ AAA lọ́jọ́ Ẹtì pé ṣe wọ́n bá ohun tó jọ mọ́ ti agbéṣùmọ̀mí lọ́wọ́ Kanu nígbà tí wọ́n mu, ó sọ pé rárá.
Ọ̀gbẹ́ni AAA fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ṣe àyẹ̀wò fóònù Nnamdi Kanu nígbà tí wọ́n mu tán àmọ́ àwọn kò gbé àbọ̀ ìwádìí náà síta nítorí pé àwọn rò pé kò ní nǹkankan ṣe pẹ̀lú ìgbẹ́jọ náà.
Ó fi kun pé àwọn ní ẹ̀rí pé Nnamdi Kanu ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìpèníjà ààbò tó ń wáyé ní ẹkùn ìlà oòrùn Nàìjíríà.
Bákan náà ni Agabi tún bèèrè lọ́wọ́ AAA pé ṣe gbogbo ìpànìyàn tó ń wáyé ní Kaduna, Zamfara, Plateau àti Benue ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú ìpè fún ìdásílẹ̀ orílẹ̀ èdè Biafra tó sì dáhùn pé rárá.
Olùjẹ́rìí náà tún sọ pé òun kò mọ ẹnìkankan tó tún ń jẹ́jọ́ ìgbéṣùmọ̀mí lórí ìpè fún ìdásílẹ̀ Biafra pẹ̀lú Nnamdi Kanu ní Nàìjíríà àmọ́ òun mọ̀ pé Simon Ekpa tó jẹ́ alátìlẹyìn fún Kanu ń kojú ìgbéjọ́ ní Finland.
“Mo mọ̀ pé DSS ń gbé ìgbésẹ̀ láti gbe padà sí Nàìjíríà láti wá kojú ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ níbí.”
Ó ní àwọn fídíò wà tó ṣàfihàn bí Nnamdi Kanu ṣe ń sọ fáwọn èèyàn láti máa ṣe ìkọlù, kí wọ́n sì máa ba àwọn dúkìá tó jẹ́ ti ìjọba jẹ́.
Àmọ́ nígbà tí agbẹjọ́rò Kanu tún bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé ṣe wọ́n ti mú ẹnikẹ́ni tó ń ba dúkìá jẹ́ nítorí àṣẹ tí Nnamdi Kanu fún wọn, ọ sọ pé rárá.
Adájọ́ tó ń gbọ́ ìgbẹ́jọ́ náà, James Omotosho sún ìgbẹ́jọ́ náà sí ọjọ́ Kẹfà, Keje àti Kẹjọ, oṣù Karùn-ún fún ìtẹ̀síwájú ìgbẹ́jọ́ náà.
Omotosho ṣèlérí láti ri pé ìgbẹ́jọ́ náà yá kíákíá nítorí ó ti ọdún mẹ́wàá tí ìgbẹ́jọ́ náà ti bẹ̀rẹ̀.
Kanu, olórí àwọn tó ń pè fún ìdásílẹ̀ Indigenous People of Biafra (Ipob), ikọ̀ kan ní ẹkùn ìlà oòrùn Nàìjíríà tó ń pè fún ìdásílẹ̀ orílẹ̀ èdè wọn.
Àmọ́ ìjọba Nàìjíríà ti kéde wọn gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ agbéṣùmọ̀mí.
Ẹ̀sùn kìíní: Sọ pé Nnamdi Kanu, gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ àti adarí Ipob wu ìwà ìgbéṣùmọ̀mí tako ìjọba Nàìjíríà nípa ṣíṣe ìkéde tó le ní ipa lórí aráàlú.
Ẹ̀sùn kejì: Sọ pé Nnamdi Kanu, gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ àti adarí Ipob wu ìwà ìgbéṣùmọ̀mí tako ìjọba Nàìjíríà nípa sísọ fún àwọn aráàlú láti máa jòkòó sílé lọ́jọ́ iṣẹ́.
Ẹ̀sùn kẹta: Sọ pé Nnamdi Kanu kéde ara à rẹ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ àti adarí Ipob lẹ́yìn tí ìjọba ti fòfin dè wọ́n.
Ẹ̀sùn kẹrin: Sọ pé Nnamdi Kanu ṣe ìkéde níbi tó ti ń ṣe àtìlẹyìn fáwọn èèyàn láti máa pa ẹ̀ṣọ́ ààbò Nàìjíríà.
Ẹ̀sùn karùn-ún: Sọ pé Nnamdi Kanu ṣe ìkéde níbi tó ti ń sọ fún àwọn ẹgbẹ́ rẹ láti máa ṣe ìkọlù sáwọn ọlọ́pàá Nàìjíríà.
Ẹ̀sùn kẹfà: Sọ pé Nnamdi Kanu ṣe ìkéde níbi tó ti ń ṣe àtìlẹyìn fáwọn èèyàn láti máa ìkọlù sáwọn ohun ìní ìjọba àpapọ̀ tó wà ní ìpínlẹ̀ Eko.
Ẹ̀sùn keje: Sọ pé Nnamdi Kanu gbé rédíò kan tí wọ́n mọ̀ sí Tram 50L wọ Nàìjíríà tó sì gbe pamọ́ sí Ubulisiuzor ní ìjọba ìbílẹ̀ Ihiala ní ìpínlẹ̀ Anambra.