A kò jẹ̀bi ẹ̀sùn ìkọlù ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíkì – Àwọn afurasí sọ fún adájọ́
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣé wọ́n ní bí ọ̀rọ̀ ńlá ò bá tí ì tán, èèyàn ńlá ò ní-ín sinmi.
Àwọn afurasí márùn-ún tí wọ́n furasí pé wọ́n wà nídìí ìkọlù tó wáyé ní ilé ìjọsìn Kátólìkì St Francis ní ìlú Ọwọ lọ́dún 2022 tí sọ fún ilé ẹjọ́ pé àwọn kò jẹ̀bi ẹ̀sùn náà.
Ijọba apapọ n fi ẹsun mẹsan an to da lori igbesunmọmi kan awọn marun un naa niwaju Onidajọ Emeka Nwite ti ile ẹjọ giga apapọ kan ni ilu Abuja lọjọ Aje.
Ijọba apapọ tun sọ niwaju ile ẹjọ ọhun pe awọn afurasi naa, Idris Omeiza, Al-Qasim Idris, Jamiu Abdul Malik, Abdulhaleem Idris ati Momoh Abubakar, wa lara ikọ agbesunmọmi labẹ ẹgbẹ Al-Shabab ni ipinlẹ Kogi.
Onidajọ Nwite ti sun itẹsiwaju igbẹjọ naa si ọjọ kọkandinlogun lọdun 2025.
Bakan naa ni adajọ naa tun paṣẹ ki wọn fi awọn afurasi naa pamọ si akoso awọn agbofinro DSS.
Igbẹjọ awọn afurasi naa n waye lẹyin ọdun mẹta ti olori ileeṣẹ ọmọogun nigba naa, Ọgagun agba Lucky Irabor kede pe ọwọ ti tẹ awọn afurasi to kọlu ile ijọsin naa ti wọn si gbẹmi awọn olujọsin to le ni ogoji lẹyin ti wọn ṣina ibọn bolẹ lasiko ijọsin.
Igbimọ eto abo ni Naijiria ti ṣaaju sọ wi pe awọn ọmọ ẹgbẹ agbesunmọmi ISWAP lo w ani idi ikọlu naa.