A kábàámọ̀ pé a polongo ìbò fún Tinubu – Lalude

A kábàámọ̀ pé a polongo ìbò fún Tinubu – Lalude

Mary Fágbohùn

Gbajumo osere tiata, Lalude ti safihan pe oun ati awon akegbe oun miran gba egberun mewaa naira owo ounje ojoojumo lati polongo ibo fun Aare Tinubu lodun 2023.

Lalude so eyi nigba to n fi ika abamo bonu lori atileyin to se fun ijawe olubori Tinubu ninu eto idibo ohun.

Nigba to n soro ninu iforowero kan to n lo kaakiri lori ayelujara, osere naa salaye pe osu kan ati ose meta lohun ati awon akegbe oun bii meloo kan fi se ipolongo ipo laigba sile kan.

Lalude to koro oju si abajade ohun ti won se ohun ni egberun mewaa naira pere ni won gba bii owo ounje lojoojumo, won o si tii gba eyikeyi ere lati bi odun meji ti Tinubu ti wa lori alefa.

“Won kan n fun wa ni egberun mewaa lati fi jeun lojoojumo ni. O ye ko ju bee lo fun ipolongo, sugbon won pinnu lati fun wa ni egberun mewaa. Nigba ti won ri pe a n fi owo naa pamo, won din iye owo naa ku, nigba miran won o ni fun wa ni nnkankan lojo meji si meta.

“Leyin gbogbo ise ipolongo ipo fun osu kan ati ọsẹ meta, won ko lati sanwo fun wa. Gbogbo awon ti won fi anfaani to ye ka je mu ko ni soriire laye won,” Lalude so bee.

Osere naa soro leyin ojo die ti akegbe re, Alapini, ni oun kabamo ipolongo ibo yii.

Odun meji niyi leyin ti a dibo yan Aare.
E ranti pe pupo ninu awon ilumooka ni won kede atileyin fun Tinubu ninu eto idibo to koja bii Saheed Balogun, Bimbo Akintola, Toyin Abraham, Eniola Badmus, Olaiya Igwe, Seyi Law ati awon miran.

Wayi o, abajade re ko te opolopo awon omo Naijiria lorun, pelu awuyewuye to n jeyo lori ikanni ibanidore, pelu bi opolopo se yera fun won ti won si bu enu ate lu ipinnu won nitori bi eto oro aje se denukole ati aisiaabo to peye labe isejoba Muhammadu Buhari pelu awon asejoba labe egbe oselu All Progressives Congress (APC).