Aṣẹ́wó àti onífàyàwọ́ máa bẹ̀rẹ̀ sí ní san owó orí – Taiwo Oyedele

Aṣẹ́wó àti onífàyàwọ́ máa bẹ̀rẹ̀ sí ní san owó orí – Taiwo Oyedele

Ìròyìn òwúrọ̀

Ni Naijiria ti oni, ilu ti yi orin ti yi pada. Awọn to n se owo nabi ti gbogbo eniyan mọ si aṣewo maa bẹrẹ si ni san owo ori lati ọdun 2026 yii.
Ori ẹrọ ori tẹlifisọn Channels ti Ṣẹgun Okinbaloye n dari ni Ọgbẹni Taiwo Oyedele to mọ tifun-tẹdọ owo ori ti n salaye, nigba ti Okinbaloye beere pe ise Aṣẹwo ati fayawọ jẹ awọn isẹ ti ijọba ko fọwọ si to lodi sofin, bawo ni iru ijọba ti ko fọwọ si isẹ ṣe tun maa gba owo ori iru iṣẹ bẹẹ?
Oyedele ni ti wọn ba ti sise naa de ibi ti ere ti di gọbọi, won ni lati san owo ori.
Mọto, irẹsi tabi ọja fayawọ miiran to gbọna ẹburu wọle ba ti jẹ ere ti o gọbọi de odiwọn owo ori, ijọba maa gbaa.
Oyedele ni gbogbo eto lo si ti wa nilẹ lati ma se jẹ ki awọn eniyan parọ owo wọn mọ.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here